Iléesẹ́ Ọlọ́pàá: Ọwọ́ wa ti tẹ afurasí márùn-ún lórí ẹ̀sùn náà

Owo beba Naira

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ileesẹ ọlọpaa ti wa rọ awọn ara ilu lati maa sọra se nipa awọn eeyan ti wọn yoo maa tọ lọ fun aajo ẹmi

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ́ Ọ́sun ti kede pe, ọwọ ti tẹ eeyan marun-un lori ẹsun pe wọn lu olori ile asofin ni ipinlẹ Ọsun, Hon Timothy Owoẹyẹ, ní jibiti owó tó lé ní miliọnu mejidinlogoji naira, ti gbogbo wọn si ti foju ba ile ẹjọ.

Atẹjade kan ti alukoro ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọsun, Fọlasade Aduro fọwọsi lo sisọ loju ọrọ yii, to si tun kede orukọ awọn afurasi to wa nidi ẹsun naa.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti wi, orukọ̀ awọn afurasi onijibiti naa ni Kazeem Agbabiaka Ajetumobi, Alhaji Femi Oyebode, ti gbogbo eeyan mọ si "Atona", Abdul Rassheed Ojonla, to tun n jẹ "Apase Oodua", Babatunde Oluajo ati Adebiyi Kehinde Oseni ti adape rẹ́ tun n jẹ "Jagun".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

OsunDecides: Omisore ní ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò, àwọn yóò lọ lásọ mú ni

Atẹjade naa tun salaye pe, bi o tilẹ jẹ pe awọ̀n afurasi gbajuẹ naa ti wa ni ahamọ ọlọpaa, sibẹ awọn si tun n wa awọn eeyan kan to tun lẹbọ lẹru lori isẹlẹ yii. Lara awọn afurasi miran ti awọn ọlọpaa naa ni awọn n wa ni Alhaja Sekinat, ti wọn n pe ni "Iyalaje ilu Oyo" ati Sunkanmi Onikoko ti Ile-Ife.

Atẹjade naa ni ọkunrin kan ti wọ̀n n pe orukọ rẹ ni Kazeem Agbabiaka Ajetunmọ̀bi, to n gbe nilu Oke-mẹsi Ekiti, lo ransẹ pe asofin Timothy Owoẹyẹ, to si fi han awọn eeyan kan to ni wọn yoo se iwẹnumọ fun-un. Amọ Owoẹyẹ ni lẹyin-o-rẹyin, oun ko mọ ohun ti oun n se mọ, ti wọn si fi oogun gba owo to le ni miliọ̀nu lọna mejidinlogoji naira lọwọ oun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Owoẹyẹ ni oun ko mọ ohun ti oun n se mọ, ti wọn si fi oogun gba owo to le ni miliọ̀nu lọna mejidinlogoji naira lọwọ oun.

Ileesẹ ọlọpaa ni asofin Owoẹyẹ, lati ipasẹ agbẹjọro rẹ, to fi ọrọ naa to ileesẹ ọ̀lọpaa leti, tun fi kun pe, awọn afurasi onijibiti naa tun gbe oun lọ si abule Ọsunjẹla, nibiti wọn ti lu oun ni aludojubolẹ, ti wọn si da apa si oun lara, bẹẹ́ ni wọn tun bọ asọ lọrun oun, ti wọn si ya fọto ihoho oun, eyi ti wọn fi n gba owo lọwọ oun.

Ileesẹ ọlọpaa ti wa rọ awọn ara ilu lati maa sọra se nipa awọn eeyan ti wọn yoo maa tọ lọ fun aajo ẹmi, nitori awọn gbajuẹ naa ti n se bi eeyan Ọlọrun.

Afegbua yọju sileesẹ ọlọpaa

Ninu iroyin miran ẹwẹ, Ọgbẹni Kassim Afegbua, to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ ologun tẹlẹ ni Naijiria, Ibrahim Babangida ati awon agbejoro rẹ ti yoju sileesẹ ọlọpa nilu Abuja.

Ni nnkan aago mewa aro lojooru ni Afegbua, ti ileesẹ ọlọpaa kede pe wọn nwa sepade pelu awon oga olopa naa.

Kayode Ajulo, to je agbẹjọrọ fun ọgbẹni Afegbua so fun ileesẹ BBC pe ipade oun lo ni iroworose ati pẹ nsẹ ni awọn asoju oga agba ile isẹ ọlọpa to gba awon lalejo, n toro aforijin fun isele naa.

Kayọde Ajulọ tesiwaju pe ''bi a ba pada de ile,ao se agbeyẹwo oro naa ki a to le so igbese to ba kan. Sugbon lai dena penu, awọn ta ba pade nileesẹ ọlọpa so pe, ede aiyede ni ohun to sele yi, to si ye ka yanju re lai si wahala kankan.''

Oríṣun àwòrán, Kayode Ajulo

Àkọlé àwòrán,

Ajulọ ni lẹyin agbeyẹwo ipade yi lawọn yoo to sọ ohun to kan

Bẹẹ́ ba gbagbe, Ogbeni Afegbua pe alukoro ileesẹ ọlọpa, Jimoh Moshood ati awọn ileesẹ iroyin meji mii lẹjọ ibanilorukọ jẹ.

O pe ẹjọ yii nile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja lọsan ọjọ isẹgun.

Oríṣun àwòrán, Kayode Ajulo

Àkọlé àwòrán,

Agbejoro Afegbua ni eni to ba sẹ, lo ma'n saa

Leyin igbana, ni awon agbejọro re fi iwe sowo si ile ejo giga nilu Abuja wi pẹ awọn setan lati yo oruko ileesẹ mohunmaworan apapọ ti Naijiria, NTA ati channels kuro ninu ejo naa.

Sugbon won ni awon yoo yoju si ileese olopa to kede orukọ rẹ gẹgẹbi ẹni ti wọn nwa ni kiakia pẹlu ẹsun pe o gbe ayederu iroyin sita.

Akitiyan wa lati ba alukoro ile ise ọlọpaa Jimoh Moshood sọrọ lori isẹle naa lo ja si pabo pẹlu bi ko se gbe ipe wa.