Benue: Ile asofin ni ọga ọlọpa Nigeria ko kajuẹ‘

Ibrahim Idris, ọga agba ọlọpa Naijiria Image copyright @PoliceNG
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ Naijiria lo n fajuro lori ọpọ aifararọ eto aabo lawọn agbegbe kan

Ile asoju-sofin lorilẹede Naijiria ti kesi aarẹ Muhammadu Buhari lati gba isẹ lọwọ Ibrahim Idris tii se ọga agba fun ileesẹ ọlọpa orilẹede yi nitori pe ko kajuẹ.

Ile ni o kuna lati koju ipenija eto aabo to n waye ni Naijiria, paapa julọ, iwa isekupani awọn darandaran Fulani nipinlẹ Benue ati aifararọ eto aabo nipinlẹ Kano.

Awọn asofin naa fohun sọkan bẹẹ lẹyin ijiroro wọn lori aba meji, eyi to nii se pẹlu iwa isekupani awọn darandaran nipinlẹ Benue ati idi to fi yẹ lati pinwọ iwa janduku lagbo oselu nipinlẹ Kano ati lorilẹede Nigeria lapapọ.

"A n fẹ ki aarẹ Buhari tete yọ ọga agba ọlọpa bii ẹni yọ jiga, ko si paarọ rẹ pẹlu ọga ọlọpa to kunju iwọn."

Bakanaa ni ile tun kesi Idris lati tọrọ aforijin lọwọ Gomina Ortom

Nigba to n kadi ijiroro naa nilẹ, olori ile, Ọgbẹni Yakubu Dogara ni "taa ba fi fọwọsi atunse awọn aba mejeeji yi, itumọ rẹ ni pe gbogbo awọn asoju-sofin n panupọ kede pe awọn ko nigbẹkẹle ninu ọga agba ọlọpa lorilẹede yi."

Bakanaa ni ile tun pasẹ fun ọga agba ọlọpa pe ko tọrọ aforijin lọwọ gomina ipinlẹ Benue, Ọgbẹni Samuel Ortom lori bi agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa orilẹede yi, Jimoh Yusuff ti sapejuwe gomina Ortom bii ẹni to n ri lagbo oselu.