Super Eagles: Akojọpọ aworan asọ fun ife ẹyẹ agbaye

Asọ ere bọọlu Super Eagles tuntun Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Osu kẹta ọdun 2018 ni Super Eagles yoo wọ jẹẹsi tuntun yi fun igba akọkọ

Ajọ elere bọọlu ilẹ wa, NFF ati ileesẹ Nike ti safihan asọ ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles yoo wọ lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye 2018, ti yoo waye lorilẹede Russia faraye.

Sugbọn awọn ọmọ orilẹede yi ko tii sọ ero ọkan wọn nipa asọ ọhun.

Biotilẹjẹpe ero awọn ọmọ Naijiria se ọtọọtọ, bi asọ naa se jọ eyi ti ikọ Golden Eagles wọ nibi ifarahan wọn akọkọlasiko ipolongo fun idije ife ẹyẹ agbayelorilẹede Amẹrika lọdun 1994, lo seese ko mu ki awọn ololufẹ Super Eagles mase kọbi ara sii.

Bakanaa ni wọn tun si asọ loju eegun nipa ‘jẹẹsi‘ ti Super Eagles yoo wọ nibudo igbaradi wọn, ti iroyin kan si ni wọn yoo maa ta awọn asọ yi losu kẹrin si ikarun ọdun 2018.

Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Asọ olomi aro yi dara pupọ lọrun Mikel Obi

Ileesẹ Nike lo gba ipo Adidas, to n ran asọ fun Super Eagles tẹlẹ

Orilẹede Naijiria nlo ileesẹ aransọ Nike lati pese asọ ere bọọlu fun Super Eagles lẹyin ti ileesẹ aransọ Adidas ti pese asọ jẹẹsi fun ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ wa naa fun ipolongo idije ife ẹyẹ agbaye meji gbako, eyiun lọdun 2010 ati 2014.

Ọjọ kẹtalelogun osu kẹta ọdun 2018 ni Super Eagles yoo wọ asọ naa fun igba akọkọ nigbati wọn ba n waako pẹlu akẹẹgbẹ wọn lati orilẹede Poland ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹnilu Warsaw

Ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Croatia, Iceland ati Argentina ni Super Eagles yoo maa ba figa-gbaga ni igun kẹrin nibi idije ife ẹyẹ agbaye naa.

Akojọpọ awọn aworan ‘jẹẹsi’ Super Eagles naa ree:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSuper Eagles: Akojọpọ aworan asọ fun ife ẹyẹ agbaye
Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Asọ tẹgbẹ Super Eagles wọ nibi idije ife yẹ agbaye lọdun 1994 jọ tdun 2018
Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Orilẹede Croatia, Argentina ati Iceland ni Super Eagles yoo koju ni igun kẹrin idije ife ẹyẹ agbaye
Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Nike ni wọn se asọ ọhun lọna ti yoo fi mu ki ara awọn ọmọ Naijiria ya gaga ni
Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Ilu London ni wọn ti safihan asọ tuntun naa faraye
Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Nike ni awọn jẹẹsi tuntun yi ko ni si lori atẹ titi osu kẹfa ọdun 2018
Image copyright Nike/Twitter
Àkọlé àwòrán Gbajugbaja akọrin takasufe, Wizkid gan tẹle wọn lọ sibi ayẹyẹ afihan jẹẹsi naa