Ọwọ agbofinro tẹ ọmọ China mẹrin fun iwakusa lọna aitọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede China ni wọn wa nsisẹ iwakusa orilẹede Naijiria
Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ati China fun wiwa kusa lọna ti ko bofinmu.
Ikọ alaabo alajumọse laarin awọn ọlọpa ati ologun lo fi panpẹ ofin mu awọn ọmọ orilẹede China mẹrin pẹlu awọn ọmọ orilẹede Naijiria mẹrindinlogun miran nipinlẹ Ebonyi to wavlapa ila oorun guusu orilẹede Naijiria.
Ọrọ aje Naijiria to nsojojo, lo mu ki ijọba maa ke gbajare sita wipe ẹgbẹlẹgbẹ owo to yẹ ko wọle si apo asuwọn ijọba lo nbọ si ajadi apo nipasẹ awọn to n se iwakusa lọna ti ko bofin mu.
Ijọba ipinlẹ Ebonyi ni awọn afunrasi yoo fi oju ba ile ẹjọ
Ọkan lara awọn agba ọjẹ lẹnu isẹ ijọba nipinlẹ Ebonyi salaye fun BBC wipe, apapọ awọn eeyan naa to jẹ ogun, ninu eyi ta ti ri awọn ọmọ orilẹede China mẹrin, naa wa ninu ahamọ ọlọpa bayii.
Ijọba ipinlẹ Ebonyi ti ni awọn afunrasi naa yoo fi oju ba ile ẹjọ laipẹ.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede China ni wọn wa ni ẹka iwakusa lorilẹede Naijiria pẹlu bo se jẹ wipe amojuto to peye ko si fun ẹka naa.
Awọn alasẹ sọ wi pe awọn ti pinnu lati gbogun ti asa iwakusa lai gbasẹ ijọb, lọna a lati lee daabo bo ayika ki wọn si tun mu apo asuwọn ijọba gbe pẹẹli sii, ki eto ati ilana isẹ fun awọn osisẹ lee tubọ duro deede sii.