Saraki: Awọn asofin yẹ gbe igbẹkẹle araalu ninu wọn ro

Sẹnatọ Bukọla Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán,

Saraki gbagbọ wipe ẹka asofin orilẹede Naijiria nilo lati sisẹ lori igbagbọ araalu

Aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ni, ẹka asofin yẹ ko tubọ tẹnpẹlẹ mọ sise ohun gbogbo to tọ, lati mu ki araalu ni igbagbọ to kuna ninu wọn.

Saraki ni asiko to lati gbe igbesẹ to loorin lati ro ẹka asofin lagbara nitori riro ẹka naa lagbara lo lee mu ki eto isejọba tiwantiwa lorilẹede Naijiria duro deede.

Sẹnatọ Bukọla Saraki woye ọrọ yi nigba to n ba awọn akọwe ile asofin kaakiri ipinlẹ ati apapọ orilẹede Naijiria sọrọ nilu Abuja.

Sẹnatọ Bukọla Saraki ni ko si ani-ani pe ẹka asofin gan an ni ọpakutẹlẹ ati ipilẹ isejọba awarawa.

"Awa ni ẹka to kere ju laarin ẹka isejọba gbogbo. A si ni lati mu ki araalu ni igbagbọ to kikun ninu ẹka asofin. Mo ni igbagbọ to jinlẹ wipe agbara ẹka asofin ko si lọwọ awa asofin ti araalu dibo yan bikose lọwọ ẹyin alakoso to n se kokaari akoso ẹka yii."

Bakanaa naa ni aarẹ ile asofin agba ti gbe imọran rẹ yi soju opo ikansira Twitter rẹ.