Ọwọ ologun tẹ afurasi ọdaran ni Nasarrawa

Awọn apo ati ohun ija oloro ti wọn ba lọwọ afunrasi kan
Àkọlé àwòrán,

Igbesẹ eto aabo ijọba orilẹede Naijiria lori wahala darandaran ati agbẹ to n waye ti n so eso rere

Igbesẹ ijọba orilẹede Naijiria lati tubọ se atunto eto aabo lawọn agbegbe kan ti wahala darandaran ati agbẹ ti n waye, ti n dabi ẹni so eso rere bayii.

Ni ọjọbọ ni ọwọ awọn ọmọogun tẹ arakunrin kan ti wọn ba ibọn ati oniruru ohun ija oloro lọwọ rẹ.

Ikọ ọmọogun Naijiria ti wọn ko lọ si Maraba nipinlẹ Nasarawa lati mojuto eto aabo abẹle nibẹ lo mu arakunrin afunrasi naa lasiko ti wọn n se ayẹwọ ọkọ ati eeyan loju popo.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ologun ti bẹrẹ ayẹwo lati sawari awọn afurasi ọdaran

Arakunrin naa to pe orukọ ara rẹ ni Peter Iorlaha, ni wọn gbamu pẹlu apo to kun fun ibọn ilewọ alatọwọda meji, ibọn agbelẹrọ kan pẹlu ọta ibọn lorisirisi, fitila oyinbo meji, awọn oogun abẹnu gọngọ ati erọ ibanisọrọ ilewọ kan.

Laipẹ yii ni ileesẹ ọmọogun Naijiria kede lati bẹrẹ eto aabo ko-gba-gbẹrẹ kan lawọn ipinlẹ bii Benue, Taraba, Kogi, Nasarawa, Kaduna ati Niger lati lee wagbo dẹkun si gulegule isẹlẹ ijinigbe, ikọlu darandaran ati agbẹ olohun ọsin atawọn iwa ọdaran miran.

Àkọlé àwòrán,

Ileesẹ ọmọogun ofurufu Naijiria pẹlu ti da si ọrọ aabo lagbegbe aringbungbun ariwa Naijiria

Eyi si waye lẹyin ti Aarẹ Buhari ti pasẹ fun ileesẹ ọmọ ogun atawọn agbofinro lati fin gbogbo awọn onisẹ ibi lagbegbe naa jade.

Bakanna ni ileesẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria pẹlu ti kede wipe laipẹ ni wọn yoo se idasilẹ awọn ọwọ ileesẹ ọmọogun ofurufu tuntun si ipinlẹ Taraba, Benue ati Nassarawa.

Oludari ileesẹ ọmọogun ofurufu, Ọgagun Sadique Abubakar salaye wipe eyi kun ara igbesẹ to n lọ lọwọ lati koju gulegule ikọlu darandaran ati agbẹ lagbegbe naa.