Buhari fọwọsi aba igbimọ onidajọ lati yọ adajọ meji nipo

Ibori awọn amofin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ pẹ tẹnu ti n kun ọpọ adajọ Naijiria lori ẹsun iwa ibajẹ

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti buwọlu iwe asẹ ifẹyinti tipatipa lẹnu isẹ fun adajọ kan, ti wọn yoo si tun yọ ekeji nipo.

Awọn adajọ mejeeji ọhun ni Adajọ Adeniyi Ademọla, tileẹjọ giga apapọ to wa nilu Abuja, ti wọn fun ni asẹ ifẹyinti tipatipa pẹlu Adajọ O.O Tokode, tileẹjọ giga apapọ to wa nilu Benin, ti wọn yọ kuro lẹnu isẹ.

Aarẹ Buhari Buwọlu aba igbimọ eleto idajọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lori awọn adajọ mejeeji yii nibamu pẹlu ẹsẹ akọkọ abala ofin ọọdunrun o din mẹjọ, iwe ofin ilẹ wa tọdun 1999.

Igbimọ onidajọ tun daba pe, yatọ si pe wọn yọ adajọ Tokode nipo, o tun gbọdọ da gbogbo owo osu ati ajẹmọnu gbogbo to gba lọna lọna ti ko bofinmu laarin ọjọ keji osu kejila ọdun 2015 ti wọn bura fun un gẹgẹbi adajọ ileẹjọ giga si asiko ti wọn yọọ nipo pada fun ijọba.

Atẹjade kan to wa loju opo ikansiraẹni tuwita ti aarẹ orilẹede Naijiria tun kede wipe, aarẹ Buhari ti bẹrẹ igbesẹ lati ri pe awọn adajọ to pegede, fi gbọọrọ jẹka nikan ni igbimọ onidajọ n yan sipo adajọ.

Ẹnu ti n kun ọpọ onidajọ lorilẹede Naijiria fun igba diẹ bayii, paapaa julọ lẹyin tawọn osisẹ ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria, DSS, kọlu ile awọn adajọ kan loru, lọdun 2016 pẹlu ẹsun pe ejo wọn lọwọ ninu lori awọn ẹsun iwa ibajẹ ati ijẹkujẹ gbogbo.