Lagos Marathon: Abraham Kiprotich se ipò Kíní ninu ìdíje ọ̀uń

Abraham Kiprotich

Oríṣun àwòrán, Twitter.com

Àkọlé àwòrán,

Kiprotich gba aadọta ẹgẹrun dọla gẹgẹ bi ẹbun fun sise ipo kíní

Ayẹ̀yẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu lẹyin ti awọn oludije ati awọn akopa miiran ti n de ibudo ayẹyẹ fun idije ọun ti awọn ti wọn jawe olubori si ti foju han.

Eni ti o se ipo kini ninu idije ọun ni Abraham Kiprotich ti o jẹ ọmọbibi ilẹ Faranse sugbọn ti o n soju orilẹede Kenya. Ó jẹ ẹbun aadọta ẹgbẹrun dola. Kiprotich pari ere ọun ti o jẹ ogoji ati meji kilomita ni iwọn wakati meji, isẹju mọkanla ati isẹju aaya mẹrin.

Oríṣun àwòrán, twitter.com

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ orilẹede Ethiopia lo se ipo kini labala awọn obirin

Obirin akọkọ to gbegba oroke ninu ididje ọun ni Herpha Guta lati orilẹede Ethiopia.

Ilya Pam ni ọmọ orilẹede Naijiria to gbegba oroke ni abala ti idije abẹle.

Awọn eniyan mejeeji ti wọn bọ si ipo keji ati ipo kẹta naa wa lati orilẹede Kenya.

Orisirisi awọn eniyan lọmọde lagba ni wọn kopa ninu idije ọun. Awọn ọdọmọde meji, ọmọ ọdun mẹjọ ati ọmọ ọdun mọkanla ti wọn kopa ni wọn gbiyanju lati rin kilomita mejilelogun.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọdọmọde meji yii se bẹbẹ ninu ere asayipo ọun

Nigba ti o n sọ̀rọ̀ nibi ayẹyẹ ọun, Gomina ipinlẹ̀ Eko, ọ̀gbẹ́ni Akinwumi Ambode sọ pe, awọn o gbiyanju lati rii pe akopa ọmọ orilẹede Naijiria lo gbegba oroke ninu ididje ti ọdun to n bọ̀.