Buhari: Ajọsepọ Nigeria pẹlu China gboopọn sii

Aarẹ Xi Jinping ti orilẹ̀ede China ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ajọsepọ ọlọrẹsọrẹ laarin orilẹede China ati Naijiria ti gboopọn si lẹnu lọwọ yii

Aarẹ Buhari ti ransẹ ikini ku ọdun si aarẹ Xi Jinping orilẹede China ati gbogbo eeyan orilẹede ọhun ku ọdun fun ti ayẹyẹ ọdun tuntun wọn to yoo waye laipẹ.

Ninu lẹta to kọ ransẹ si Aarẹ Xi Jinping, Aarẹ Buhari ni ninu ọdun ti wọn lo kọja lọ, awọn igbesẹ to loorin ni orilẹede China gbe lẹka ọrọ aje, isejọba tiwa-n-tiwa ati ajọsepọ ilẹokeere.

Itẹjade ti agbẹnuso fun aare Naijiria, Femi Adesina, fi sita so wipe: "Aseyori ipade apapọ ẹgbẹ oselu Communist Party of China, CPC ti si ilẹkun fun akoko ọtun fun orilẹede China gẹgẹbi asiwaju ninu isẹ arojinlẹ, eto aabo, eto ile'sẹ lugbẹ, ipese ohun amuludun ati ipesẹ isuna fun idagbasoke lagbaye."

Bakanaa ni aarẹ orilẹede Naijiria tun gboriyin fun bi ajọsepọ ọlọrẹsọrẹ laarin orilẹede China ati Naijiria lẹka oselu, ọrọ aje, asa ati ọrọ ilu se n gboopọn sii.

Orilẹede China bẹrẹ ayẹyẹ ọlọkan-o-jọkan to kangun si ajọyọ ọdun tuntun rẹ ti yoo waye ni ọjọ kẹrindinlogun osu keji, ọdun 2018.

Orilẹede China wa lara awọn orilẹede ti ko fi gbogbo ara rọ mọ ounka ọjọ ti gẹẹsi ti ọpọ n lo loni.

Dipo ounka ọjọ yii, ounka ọjọ olosu mẹtala Lunar ni orilẹede China n lo; ọdun tuntun wọn yoo si bẹrẹ ni aarin osu keji ọdun 2018.