Ikọ ọmọ ogun Naijiria ni awọ̀n sọsẹ́ fun Boko Haram ni Gonori

Ikọ ọmọ ogun Naijiria
Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ duro digbí, wọn koju Boko Haram

Awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria labẹ 'operation Deep Punch' ni awọn ba ikọ Bokoharam wọ sokoto kan naa loni, ni agbegbe Gonori ni ipinlẹ Yobe.

Nigba ti o n ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ nilu Maiduguri, agbẹnusọ ikọ̀ ọmọ ogun ọun, ọgagun Sanni Kukashekau Usman sọ pe orisirisi awọn oun ija ni awọn gba lọwọ awọn ikọ̀ adunkoko mọni ọun, ti awọn si ba awọn ado oloro (IED) ti wọn fi dẹ panpẹ fun awọn jẹ́.

Ọgagun ọun ni awọn se awọn ọmọ ikọ Bokoharam ọun b'ọ́sẹ se n soju, ati pe nibi ti awọn ti jọ gbe pẹ́rẹ́gi ija kana, awọn ọmọ ogun meji farapa, sugbọn awọn mejeeji ọun wa ni ibi ti wọn ti n gba itọju lọwọlọwọ

O tun fi kun ọrọ rẹ pe, ni kete ti awọn agbesunmọmi ọun foju kan awọn ọmọ ogun ni nnkan bi aago mẹfa aabọ irọlẹ ni wọn síná ibọn fun awọn ọmọ ogun sugbọn ti awọn naa fi ija pẹẹta pẹlu wọn.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ síná ibọn fun ikọ Bokoharam, wọn ba ọkọ́ ti wọn fi gbe ado oloro si jẹ́

Usman tun sọ pe awọn kọlọrọsi ni awọn funra si pe wọn lo sofofo fun Boko Haram pe awọn ti kuro ni ibudo ti awọn wa pẹlu awọn irin isẹ awọn.

O ni nigba ti awọn o jẹ k'ara rọ wọn mọ ni ibuba wọn, ni awọn agbesunmọmi ọun fi n se ikọlu ni awọn igberiko lojuna ati sa'sala fun ẹmi wọn.