Ajọ CAN gboju agan si Yahaya Bello, wọn ni ki tọwọ ọmọ rẹ basọ

Yahaya Bello, Gomina ipinlẹ Kogi

Oríṣun àwòrán, @_rashidabello

Àkọlé àwòrán,

Ajọ CAN f'ohun ransẹ si Gomina ipinlẹ Kogi

Ajọ awọn onigbagbọ nilẹ Naijiria, CAN ati awọn Bisọọbu meji ti gboju agan si ọrọ ti Gomina ipinlẹ Kogi Yahaya Bello sọ lẹyin abẹwo ti wọn se si Aarẹ Buhari ni ọsẹ kan sẹyin.

Awọn Bisọọbu yii se abẹwo si aarẹ Buhari ni ile ijọba ni Abuja lati fi ero wọn han lori isejọba rẹ̀, ti wọn si sọ pe ki Buhari wa iyanju si bi ohun gbogbo ko se se deede' lorilẹede Naijiria.

Lẹyin eyi ni Bello sọ fun awọn oniroyin ni ọjọ ẹtì to kọja pe awọn ti awọn ọmọ ijọ wọn ko ri owo ji ninu ijọba Buhari lati wa fi san ìdámẹ́wàá ni inu wọn ko dun si Buhari.

Ni awọn lájọlájọ ti ọ̀rọ̀ naa o ba lara mu ba sọko ọrọ pada si Bello, wọn ni t'ójú akátá ba léwó, kii sẹnu adiyẹ la tii gbọ.

Lara awọn ajọ ti wọn fesi ọrọ fun Bello ni ajọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan, ajọ to n dẹkun iwa ajẹbanu ati ẹgbẹ ọmọ onigbagbọ nilẹ Naijiria, CAN, pẹlu ọpọlọpọ awọn eniyan ati lajọlajọ miran.

Ajọ CAN sọ pe Bello lẹtọ lati fi ero rẹ han, sugbọn nise lo yẹ ki Bello se amojuto ipinlẹ Kogi nibiti awọn osisẹ ti n gbẹmi ara wọn labẹ isejọba rẹ nitori aisan owo osu fun ọjọ́ pípẹ́, ati pe ki o koju isoro ijinigbe ni ipinlẹ rẹ.