Egbẹ oselu ANC yoo se'pade lori ọrọ Zuma lọ̀jọ̀ ajé to n bọ̀

Jacob Zuma aarẹ orilẹede South Afrika

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Egbẹ oselu ANC lagbara lati yọ Jacob Zuma nipo

Ọjọ ajé to n bọ̀ yii ni ẹgbẹ ANC ni orilẹede lorilẹede South Afrika ti kede pe oun yoo se ipade lori ọrọ pe ki aarẹ Jacob Zuma fi ipo silẹ.

Ọrọ ọun ti n ja roinroin ti ko si sẹni to mọ ibi ti igi ọrọ oun yoo wó si. Sugbọn ni bayii ti ẹgbẹ ọun ti wa pinnu lati se ipade lori ọrọ ọun ni ọjọ aje, eyi ni yoo sọ bi irinajo Zuma yoo se ri gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede South Afrika

Eni ti ireti wà pe yoo gba ipo lọwọ Zuma, Cyril Ramaphosa ni o ti n se ipade idakọnkọ lati rii pe idiwọ gbigbe ijọba kalẹ ọun ko pe ju bẹẹ lọ.

Wayi, ẹgbẹ ANC ti bẹrẹ ayẹyẹ lori ọgọrun ọdun aarẹ̀ alawọ dudu akọkọ ni orlẹede South Africa, Nelson Mandela, ẹni ti o di gbajugbaja lẹyin to fipo silẹ ni wọ́ọ́rọ́wọ́ lẹ̀yin ti o se eekan pere lori ijọba gẹgẹ bi aarẹ.

Ero gbogbo eniyan ni pe awọn alakoso ẹgbẹ ANC yoo pasẹ pe ki Zuma fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi aarẹ.