ICC pari iwadi lori iparun awọn Shiites, IPOB

Iwode awọn ọmọ ẹgbẹ Shiites Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ICC sọ pe awọn ti pari isẹ iwadi nipa ipakupa awọn ọmọ ẹgbẹ Shiites ati IPOB

Ile ẹjọ tohun gbẹjọ iwa ọdanran lagbaye (ICC) sọ pe awọn ti pari isẹ alakọkọ lori iwadi nipa ipakupa awọn ọmọ ẹgbẹ Shiites ati IPOB ti awọn si ti fi sọwọ si Abubakar Malami, eyi ti o jẹ minisita fun ọrọ igbẹjọ loriede Naijiria.

Awọn agbẹnusọ fun ile ẹjọ ti o gbẹjọ iwa ọdanran lagbaye naa sọ wipe wọn gbẹkẹle awọn ikanni alaye rẹpẹtẹ, pẹlu awọn ipinnu abajade ọrọ ti ijọba ti Kaduna ti ṣeto rẹ.

Igbimọ oluwadi naa ri wipe ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun Naijiria to fi mọ Ọgagun Niyi Oyebade to jẹ olori ikọ ọmọogun Naijiria kinni lasiko igba naa lọwọ si iṣekupani naa, o si tun daba rẹ wipe ki wọn o fi oju wọn wina ofin

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ICC bere fun itusile olori ẹgbẹ Shiite, Ibrahim El-Zakzaky to wa lahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS

Ẹgbẹ Shiite ni awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ to le ni ẹgbẹrun kan lo j'ọlọrun nipe lasiko ikọlu naa to waye laarin ọjọ kejila si ikẹrinla osu kejila lolu ile ẹgbẹ rẹ to wa ni Zaria.

Aṣoju ijọba ipinlẹ Kaduna sọ fun igbimọ oluwadi naa wipe ojilelọọdunrun ati meje oku ni ileeṣẹ ologun jọwọ fun isinku aṣepapọ.

Ṣugbọn tako ẹri naa, ileeṣẹ ologun ni ọmọ ẹgbẹ Shiite meje pere to di opopona ilu, to si tun gbidanwo lati pa ọga awọn, Ọgagun Tukur Buratai lawọn pa.

O ni ikọ awọn ọmọ ogun lo iwa ipa nigba to di mimọ pe ẹmi ọgbẹni Buratai wa ninu ewu.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọlu ẹgbẹ IPOB ati awọn ọmọ ogun Naijiria mu ọpọ ẹmi lọ

Olori ẹgbẹ Shiite, Ibrahim El-Zakzaky, ti awọn ọmọ ogunmu lasiko naa wa lahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fun ọdun meji o le tako asẹ ti ile ẹjọ pa wipe ki wọn o tuu silẹ lẹyẹ o sọka lọdun 2016.

Bi olori arojọtakoni ile ẹjọ ICC ba fi buwọlu pe ki wọn o f'oju wọn wina ẹjọ, yoo jẹ igba akọkọ ti ọmọ Naijiria yoo jẹjọ lori hihu iwa ọdaran si ọmọniyan niwaju ile ẹjọ naa.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Shiites, ti o ba BBC Yoruba sọrọ salaye wipe awọn ko tii gba ọrọ yi lati ile ẹjọ naa, ati wipe ti awọn ba riigba, awọn yoo se apero lori rẹ lati fi atẹjade sita lori rẹ pẹlu.