Ọyọ: Ọmọ ẹgbẹ APC fariga lori ibo ijọba ibilẹ

Oludibo kan n yẹ ika rẹ wo lori ẹrọ kaadi idibo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ ẹhonu lo n waye lori ibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna nipinlẹ Ọyọ

Ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọya ya bo olu ile ẹgbẹ oselu naa to wa ladugbo Oke Ado nilu Ibadan lati tako bi awọn alasẹ ẹgbẹ oselu ọhun se n gbe awọn oludije kan le wọn lori lọna aitọ ni igbaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye kaakiri ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalegbọn to wa nipinlẹ Ọyọ.

Awọn oluwọde naa, ti wọn wa pẹlu awọn asoju lati ijọba ibilẹ kọọkan nipinlẹ ọhun lo n kọ oniruuru orin ẹhonu, ti wọn si tun gbe oniruuru akọle lọwọ lati tọka si ẹdun ọkan wọn.

Lara awọn ohun ti wọn kọ sinu akọle ti wọn gbe lọwọ ni " Awa ko ni faramọ ole ojukoroju lọsan gangan", "Gbogbo wa la ni ẹgbẹ oselu APC", "Ogun gbogbo wa ni ẹgbẹ oselu yi", "Ẹ ma ba ẹgbẹ oselu yi jẹ mọ wa lori" ati bẹẹbẹẹ lọ.

Awọn oluwọde naa si tun gbe lẹta kan lọwọ eyiti wọn pe akọle rẹ ni 'eto idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọyọ', eyiti wọn gbero lati fi sọwọ si alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ, Oloye Akin Ọkẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ to nse kokari ibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọyọ seese ko fun awọn ẹgbẹ oselu ni akoko si lati seto idibo abẹnu wọn

Ẹgbẹ oselu Apc nipinlẹ Ọyọ ni ko si iwọde kankan

Nigba ti BBC Yoruba kan si alaga ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọyọ, Oloye Akin Ọkẹ, o ni, Ko si iwọde kankan to de ọdọ oun rara.

"Ko si iwọde kankan to waye lori ibo ijọba ibilẹ rara. Laipẹ-laijinna si laa seto idibo abẹnu fun awọn oludije fun ipo alaga ati kanselọ lawọn ijọba ibilẹ ni kete ti ajọ eleto idibo fun ijọba ibilẹ (OYSIEC) ba ti sun gbedeke akoko taa fi orukọ oludije siwaju."

Bakanaa ni akọwe ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ, Mojeed Ọlaaya pẹlu kin ọrọ Oloye Akin Ọkẹ lẹyin lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ pẹlu afikun pe ẹgbẹ oselu APC yoo seto abẹnu ti ajọ OYSIEC ba ti fun wọn lọjọ sii.

Agbẹnusọ fun ajọ OYSIEC, Ọgbẹni Cosmas Ọlalekan Oni salaye fun BBC Yoruba pe ọjọ isẹgun ni ajọ naa yoo kede afikun ọjọ ti ẹgbẹ oselu kọọkan yoo fi orukọ oludije ransẹ, nitori awọn ti fun wọn ni akoko diẹ si lati lọ seto idibọ abẹnu wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌgbẹni Cosmas Oni sọrọ lori Ibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọyọ

Related Topics