Fayose: Awọn darandaran to pa Tunde ko ni lọ lai jẹjọ

Darandaran fulani kan duro pẹlu agbo ẹran rẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gulegule awọn darndaran fulani ti da oniruuru ipaya silẹ kaakiri orilẹede Naijiria

Awọn daradaran kan ti wọn funrasi gẹgẹbi fulani ti pa rakunrin ọmọ ọdun mejilelọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Tunde Ọlayẹmi ni ilu Ipao Ekiti ni ipinlẹ Ekiti.

Ni ọsan ọjọ aiku ni wọn pa arakunrin naa lasiko to n pada bọ lati oko rẹ.

Ọmọ meji ni oloogbe Ọlayẹmi bi, oun pẹlu ẹnikan ni wọn lọ si oko ẹgẹ to gbin si igbo ọba to wa nilu naa.

Gẹgẹbi iroyin se sọ, bi wọn se n bọ silẹ lori okada lawon darandaran fulani naa sa dede yọ si wọn pẹlu ibọn.

Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Ni ibẹrẹ ọdun 2018 ni Gomina Fayose ti ipinlẹ Ekiti se ipade pẹlu awọn ọdẹ ni ilu Ado Ekiti

Bi wọn si ti se n salọ lawọn fulani naa mu Tunde, ti wọn si sa a yannayanna.

Ohun ti gomina ipinlẹ Ekiti sọ lori isẹlẹ naa

Ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ni ọwọ yoo ba eniyan yoo wu to pa rakunrin Ọlayẹmi, yoo si fi oju wina ofin.

Gomina Fayose ke si ijọba apapọ lati ji giri si ọrọ abo ẹmi ati dukia paapaa julọ 'lọwọ awọn ọdaran to n pe arawọn ni darandaran ti wọn ti wa sọ ara wọn di adukulajamọni .

"Labẹ isejọba mi ni ipinlẹ yii, ko si ẹnikẹni ti yoo pa eniyan ti yoo si lọ bẹẹ lai foju ba ofin. Gbogbo awọn to pa Ọlayẹmi Tunde ni Ipao Ekiti lana, yala wọn jẹ darandaran tabi ohun yoo wu ti wọn lee jẹ, ọwọ ofin yoo tẹ wọn wọn o si jiya to tọ niwaju ofin. Mo ba idile rẹ kẹdun."

Ohun ti ileesẹ ọlọpa sọ?

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ naa, alukoro ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Ekiti DSP Adeyẹmi Albert Ademọla ni ileesẹ ọlọpa ko tii lee fi idi rẹ mulẹ boya daranadaran fulani lo se isẹ ibi naa.

O ni awọn ọlọpa ti bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọdẹ ti bẹrẹ igbesẹ ati gbogun ti awọn darandaran Fulani nipinlẹ.

"Lootọ ni wọn pa eeyan kan ni ilu Ipao Ekiti sugbọn ileesẹ ọlọpa si n se iwadi lati mọ boya darandaran fulani lo sisẹ naa tabi awọn kọ. Nitori orisirisi isẹlẹ lo ti n sẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yii to n fẹ awofin daadaa."

Awọn ọdẹ ilu Ipao Ekiti ti fariga.

Nigba to n sọrọ, olori awọn ọdẹ ni ilu naa, ọgbẹni Adebayọ Ọdẹyẹmi salaye wipe awọn ọlọdẹ ti bẹrẹ igbesẹ ati gbogun ti awọn darandaran Fulani lagbegbe naa.

"Awa o kọlu darandaran kankan lagbegbe yii sugbọn wọn ti pa eeyan kan laarin ileto wa, a si maa rii daju pe wọn o da irufẹ asọ bẹẹ soro mọ.

Akinkanju ni wa, a kii se ojo. Nitorinaa, ohun to ba gba laa fun lati daabo bo ileto wa, awọn oko wa. Wọn ti pa ọkan ninu wa, iru rẹ ko si ni sẹlẹ mọ."

Saaju asiko yii ni ibẹẹrẹ ọdun 2018 ni gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ti gbe isẹ le awọn ọlọdẹ lọwọ lati daabo bo ileto koowa wọn lọwọ gulegule ikọlu awọn darandaran fulani ni ipinlẹ̀ naa.