Lassa: Ẹnikan ku,ogoji mii wa labẹ ayẹwo l'Ọsun

Awọn Onisegun oyinbo ngbe oku alaisi kan latipasẹ ajakalẹ arun
Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ẹmi lo n sọnu sọwọ arun iba ọrẹrẹ lorilẹede Naijiria

Eeyan kan ti ku bẹẹni awọn ogoji miran wa ni abẹ isọ kaakiri awọn ibudo ifinipamọsi fun ayẹwo to wa fawọn eeyan ti wọn ba kẹẹfin pe o seese ko ni arun iba ọrẹrẹ nipinlẹ Ọsun.

Awọn ibudo ifinipamọsi fun ayẹwo awọn ti wọn kẹẹfin pe o seese ko ni arun iba lassa yii jẹ mẹta tijọba ipinlẹ Ọsun gbe kalẹ, eyi to jẹ ara igbesẹ lati dena itankalẹ arun yii.

Alaga ẹgbẹ awọn onisegun oyinbo (NMA) nipinlẹ Ọsun, Dokita Tokunbọ Ọlajumọkẹ lo salaye ọrọ yii lasiko tawọn dokita onisegun oyinbo lọ kaakiri lati seto itaniji fawọn araalu kaakiri awọn ọja to wa ni ilu Osogbo.

Oríṣun àwòrán, Baba Oloye

Àkọlé àwòrán,

Awọn dokita bẹrẹ iwọde itaniji lori wiwawọ iba lassa bọlẹ nipinlẹ Ọsun

Dokita Ọlajumọkẹ ni, biotilẹjẹ wipe ẹni tarun yii ran lọ sọrun ni ibudo ẹkọsẹ isegun fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile ifẹ, wa lati ipinlẹ Ondo, o se pataki lati tete fi gbogbo awọn to fara kanra lọna kan tabi omiran pẹlu alaisi naa sabẹ aabo, ki arun naa to tan kale-n-kako.

O tun salaye wipe iwọde itaniji naa wa lati lee mu ki araalu mọ nipa aarun yii ki wọn si mọ igbesẹ to tọ lati gbe bi wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni to nii layika wọn.