Iwa-ipa Fulani darandaran: ọlọpa fi panpẹ ọba mu eniyan meji

Maalu lorileede Naijiria
Àkọlé àwòrán,

Opolopo ijamba loti sele latari aigboraeniye laarin awon Fulani darandaran ati agbe

Ile ise ọlọpa ni wọn ti mu Fulani darandaran kan ati agbẹ oloko kan ninu isẹlẹ to waye lagbegbe guusu Akure, agbẹnusọ ajọ ọlọpa ipinlẹ Ondo fi idi rẹ mulẹ.

Agbenuso naa, Femi Joseph sọ fun BBC Yoruba wipe ọrọ naa dojuru nigbati Fulani darandaran kan fẹ ẹ wọ oko agbẹ yi, ti agbẹ naa si yari pe ohun ko ni i faaye gba Fulani darandaran na lati wọ inu oko oun.

Ọrọ naa di gbọnmisi omi o too, ti awọn osisẹ ile-isẹ ijọba ibilẹ guusu Akurẹ si yabo ibi isẹlẹ naa.

Ajọ ọlọpa ni Fulani darandaran ati agbẹ naa ti wa ni agọ ọlọpa ati wipe alaafia ti pada s'agbegbe naa.

Isẹlẹ yi ni o tẹle ọpọlọpọ iwa ipa laaarin Fulani darandaran ati agbẹ lagbegbe guusu iwọ-oorun Naijiria.

Losu to kọja, awọn Fulani darandarn da'nọ sun oko oloye Olu Falae ni ilu Akurẹ, ti won si pa awako kan lori ariyanjiyan laarin won ni ipinlẹ Ondo.

Ti a ko ba gbagbe, igbakeji aare, Yemi Osinbajo nigba to hun si ipade eto aabo ti ile igbimo asofin gbe kale, sowipe idasile olopa ipinle yoo bojuto wahala to n sele laarin awon darandaran ati agbe lorileede Naijiria.

Loni, ajo awon gomina lorileede yii faramo idasile oloopa ipinle gegebi igbakeji aare se so.

Àkọlé fídíò,

Arakunrin Fulani ni aigbede ara eni ni orisun ija pelu agbe