Aarẹ Zuma f'ipo silẹ

Aarẹ Jacob Zuma Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lẹyin p awuyewuye, Zuma kọwe fipo silẹ

Nigbakanri, wọn ti pee ni aarẹ ti ilu fẹ. Aarẹ taraye fẹ, ẹni to ti figbakanri se ẹwọn nitori awọn iha to kọ seto oselu, ko ni anfani eto ẹkọ mọọkọ mọọka sugbọn o dide goke tente si ori pepele eto oselu ni orilẹede South Africa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJacob Zuma bura wọle gẹgẹbi aarẹ orilẹede South Africa

Amọsa lati nkan bii ọdun mẹẹdogun sẹyin, orukọ Jacob Zuma koo ye farahan pẹlu iwa ijẹkujẹ.

Nibayii, ariwo araalu ti gbode kan lori ẹsun pe o faaye gba idile kan lati Guptas lati orilẹede India lati maa se baba isalẹ ati ri isẹ gba ni orilẹede SouthAfrica. Sugbọn Idile Guptas ati aarẹ Zuma ti sọ wipe ko si ootọ ninu ẹsun yii.

Lẹyin eyi ni ariwo tun sọ pe aarẹ zuma fi owo ilu tun ile rẹ to wa ni Nkandla. Eto abo ni owo yii wa fun sugbọn nkan bii ibi iwẹ igbafẹ swimming pool ati ile ikadiyẹ si ni owo yii ba lọ, Zuma ti da owo yii pada bi a se n sọrọ yii.

Atapata dide ni Zuma. ọmọ ọdọ ni iya rẹ, Jacob Zuma pẹlu figbakanri sisẹ darandaran.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ ANC yọ aga nidi Zuma nitori aisedeede ati iwa ibajẹ

Eyi si kun ara awọn ohun ti awọn araalu ri ti wọn fi dibo fun oun ati ẹgbẹ oselu rẹ, African National Congress, ANC lẹẹmeji.

Igba ewe lo ti darapọ mọ ẹgbẹ oselu ANC. Wọn si fi si ẹwọn ni erekusu Roben Islan lori ẹsun pe o ditẹ mọ ijọba amunisin to wa lode nigba naa.

Lẹyin ti wọn daa silẹ. Zuma lo ọpọlọpọ ọdun ni eyin odi gẹgẹbi atipo ki o to bẹrẹ si ni goke lagbo ẹka ologun ẹgbẹ oselu ANC.

O si jẹ ọkan gboogi lara awọn to le isejọba awọn alawọfunfun jina ti Nelson Mandela fi di aarẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrin idanimọ South Africa.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌrọ Nelson Mandela

Jacob Zuma ni igbakeji fun aarẹ Thabo Mbeki ki o to di wipe ija waye laarin wọn ti Mbeki si yọọ nipo lọdun 2015 fun ẹsun ijẹkujẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionThabo Mbeki yọ Zuma ni ipo gẹgẹbi igbakeji aarẹ.

Nkan pada se ẹnuure fun Zuma nitori wọn gbẹsẹ le awọn ẹsun yii, o si di aarẹ ẹgbẹ oselu ANC lọdun 2007 nigba ti wọn fi tipatikuuku rọ aarẹ igba naa, Thabo Mbeki loye.

Pẹlu gbogbo ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an araye tubọ n fẹ Zuma nigba naa. Lootọ ileẹjọ ni ko jọbi ẹsun yii, sugbọn Zuma funrarẹ jẹwọ wi pe lootọ loun ba obirin kan lo pọ lai lo rọba idaabobo, bi o ti lẹ jẹ wipe o mọ pe obinrin ọhun ni kokoro aarun HIV.

Image copyright Getty Images

Lara awọn awijare to yọju lasiko igbẹjọ rẹ ni ohun ti Zuma sọ wipe oun dena kiko arun naa nipa bibomi sanra lẹyin ibalopọ naa.

Eyi di orisun awada kaakiri orilẹede naa debi wipe ẹkan ninu awọn alaworan apanilẹrin lorilẹede SouthAfrica ya aworan rẹ pẹlu ori irin baluwẹ igbalode lori rẹ. Zuma fesi si awọn ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC ni ọdun 2009.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionZuma sọrọ lori iha rẹ si itankalẹ kokoro aarun HIV

Ninu ifọrọwerọ miran pẹlu BBC, Jacob Zuma gba wipe oun se asise,sugbọn o ni oun ko jẹbi ẹsun iwa ijẹkujẹ ti wọn fi kan an.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionZuma sọrọ lori boya ọdaran ni tabi ọdaran kọ

Ko si iroyin to wu ni lori nipa igbesẹ ijọba rẹ lori gbigbogun ti isẹ ati iya sugbọn awọn ololufẹ rẹ n tọka si idagbasoke lẹka eto ẹkọ plẹlu ipese ogun aarun AIDs lọpọ yan turu lasiko isejọba rẹ.

Amọsa nkan o se dede fun eto ọrọ aje lẹyin ti Zuma sa dede le minisita feto isuna rẹ lọdun 2015.

Nibi ipade apapọ ẹgbẹ oselu APC to waye laipẹ yii, Jacob Zuma kọ jalẹ lati fi ipo silẹ to si n di ẹbi ru awọn orilẹede okeere fun igbimọpọ lati yọ oun nipo.

Amọsa, awọn ọmọ ẹgbẹ oselu rẹ lo sokunfa ijakulẹ rẹ. Oniruru ipinya lo si ti waye lẹgbẹ oselu ANC nipasẹ ẹsun ti wọn n fi kan an eyoi si tun ti se akoba fun ifẹ ti araalu ni si ẹgbẹ oselu naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn oluwọde n pariwo wi pe Zuma gbọdọ fi ipo silẹ.

Ero ọpọ bayii ni wipe fun igba akọkọ ni ogun ọdun, o seese ki awọn eeyan o kọ ipakọ si ẹgbẹ oselu to lewaju ijija gbominira wọn.

Nibayii, o n jọ bi ẹnipe, wahala yoo pọ fun ẹgbẹ oselu ANC ti wọn ba gba Zuma laaye ko wa nipo di asiko idibo apapọ lọdun 2019.