Soyinka: Buhari ti wọnu ẹmi lọ

Ọjọgbọn Wọle Soyinka atawọn eeyan to n se iwọde Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aimọye igba ni Soyinka ti maa n tako asise awọn ijọba to ti kọja lọ lorilẹede Naijiria

Agba onkọwe nni, Ọjọgbọn Wọle Soyinka, ti sapejuwe aarẹ orilẹede yi, Muhammadu Buhari gẹgẹbi ẹni to ti wọnu ẹmi lọ.

Soyinka, ẹni to safihan ijakulẹ to ni nipa ohun to pe ni awọn asise afọwọfa ijọba Muhammadu Buhari , woye ọrọ yi nibi ipade kan to bawọn akọroyin se lori bi iwa ifẹhonu han se n gbinlẹ si jakejado orilẹede Naijiria, nitori ikọlu awọn darandaran agbebọn lawọn agbegbe ti awọn agbẹ tẹdo si.

Nigba to n dahun ibeere latọdọ awọn akọroyin lori ohun ti yoo sọ fun Buhari tawọn mejeeji ba foju se mẹrin ara wọn, Soyinka ni,

"Maa sọ pe, Ọgbẹni Aarẹ, o dabi ẹnipe o ti wọnu ẹmi lọ. Boo ba si se tete jade kuro ninu ẹmi si, ni yoo fi dara si. Nitori ọpọ asise lo n waye bayi".

Àkọlé àwòrán Ọjọgbọn Wọle naa ti darapọ mọ awọn ọmọ Naijiria kan lati tọkasi aleebu isejọba aarẹ Muhammadu Buhari

Ọpọ asise to kun inu ijọba Buhari lo jẹ afọwọfa

Soyinka wa mẹnuba igbesẹ bi Buhari se pe akọwe apapọ fun ajọ to nse amojuto eto adojutofo nidi ilera (NHIS), Usman Yusuff pada sẹnu isẹ, lẹyin ti minisita feto ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewọle ni ko lọ rọọkun nile na nitoripe o se owo ilu basubasu, gẹgẹ bii apẹrẹ kan to n safihan pe oniruuuru asise afọwọfa lo kun inu isejọba Buhari dẹnu.

Sugbọn awọn agbẹnusọ fun aarẹ Buhari ko tii fesi pada lori ọrọ yi. A o maa mu esi wọn wa fun yin ni kete ti wọn ba ti fesi lori ọrọ yi.

Related Topics