Ibeji to lepo ni Bauchi: Ọkan ninu re ye ninu isẹ abẹ

Awọn ibeji to lẹpọ ninu ibudo itọju pajawiri
Àkọlé àwòrán Ọpọ ibeji to lẹpọ ni wọn ti sisẹ abẹ fun jakejado to si yọri si rere

Ọmọdebinrin kan to jẹ ibeji ti ye isẹ abẹ ti wọn se fun oun ati ikeji rẹ eyi to yọri si rere lẹkun ariwa ipinlẹ Bauchi.

Awọn onisẹ abẹ meje, dokita oyinbo, atawọn olutọju alaisan mii, lo se isẹ abẹ naa, eyi to waye fun wakati meji gbako.

Awọn alasẹ nipinlẹ Bauchi salaye pe eyi to jẹ ọkunrin ninu awọn ibeji naa gbẹmi mi amọ eyi to jẹ obinrin si n gba itọju lọwọ bo se yẹ.

Akọroyin ileesẹ wa BBC, Chris Ewokor to se akojọpọ iroyin naa lati Abuja ni, osu kejila ọdun to kọja ni wọn bi awọn ibeji naa nile iwosan alabọde kan to wa ni abule Chanka, nijọba ibilẹ Aikaleri, nipinlẹ Bauchi.

Iroyin naa ni, obirin kan, ẹni ogun ọdun , lo bi awọn ibeji to lẹpọ naa, sugbọn ọkan ninu wọn ko mi rara eyi to nilo ki wọn sisẹ abẹ ni kiakia lati doola ẹmi ikeji rẹ to n mu, ki wọn si ya wọn si ọtọọtọ.

Àkọlé àwòrán Ibi gbogbo ni wọn ti nko adiẹ alẹ taa ba nsọrọ bibi awọn ibeji to lẹpọ

Iranwọ owo isẹ abẹ de fun awọn ibeji naa nigbati olori ile asoju-sofin, Hon Yakubu Dogara se agbatẹru isẹ abẹ naa, ki eyi ibeji to nmi daada naa lee gbe ile aye.

Ibi gbogbo ni wọn ti n bi awọn ibeji to lẹpọ jakejado agbaye

Bẹẹ ba gbagbe, nipinlẹ Bauchi yi kanaa lọdun meji sẹyin, mọlẹbi kan padanu ibeji to lẹpọ ni ẹsẹ mẹta nibi idodo wọn.

Bakanaa losu kọkanla ọdun 2016, awọn onisegun oyinbo fi isẹ abẹ ya awọn ibeji kan ti wọn lẹpọ amọ ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Naijiria nile iwosan Tennessee lorilẹede Amẹrika nigba to ku ọjọ diẹ ki wọn se ọjọ ibi ọdun kan.

Nibi igegeru ni awọn ibeji ọhun ti lẹpọ, eyi tawọn onisegun oyinbo ni, o maa n waye lẹẹkan ninu ibi miliọnu marun