Nigeria: Awọn asofin nwadi ibiti owo ẹyọ lọ

owo sile
Àkọlé àwòrán,

Ọwọngogo owo wẹẹrẹ ti mu isoro ba karakata awọn mẹkunnu

Awọn asofin agba lorilẹede Naijiria ti pinnu lati se iwadi lori ọwọngogo awọn owo ẹyọ lẹyin ti ile ti jiroro lori bi awọn owo wẹẹrẹ yi se jina si ikawọ awọn araalu.

Sẹnatọ Peter Nwaoboshi lo pe akiyesi awọn akẹgbẹ rẹ si isoro tawọn eeyan orilẹede Naijiria, paapaa julọ awọn mẹkunnu n doju kọ lori aisi owo ẹyọ fun wọn lati na pẹlu ọkan-o-jọkan iroyin to n sọ wipe banki apapọ orilẹede Naijiria ko tẹ awọn owo sile mọ.

Lẹyin oniruru aba ati ijiroro, awọn asofin agba orilẹede Naijiria ti wa dari igbimọ to nse amojuto banki atawọn ile ifowopamọ lati mu aba wa lori wiwa ojuutu si isoro naa.

Awọn asofin fẹ mọ iye tijọba nna lati tẹ owo ẹyọ

Ninu ọrọ rẹ, igbakeji aarẹ ile igbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Ike Ekweremadu ni, igbesẹ titẹ awọn owo nla jẹ ohun kan to n fa isoro, paapaa nilẹ Afirika eyi to n nipa ti ko tọ lara awọn owo kekeeke.

Bakanaa lawọn asofin ọhun tun pinnu lati sagbeyẹwo elo gan an lowo ti orilẹede Naijiria n na, lati ipasẹ ileesẹ itẹwo rẹ, lati fi lati tẹ owo naira.