Shekau wọ ijabu lati bọ lọwọ ologun

Abubakar shekau, asiwaju ikọ Boko Haram Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ igba lawọn ologun nkede pe Abubakar Shekau ti jade laye

Awọn ologun orilẹede Naijiria ti pariwo sita wipe olori ikọ adukukulaja mọni Boko Haram, Abubakar Shekau ,ti na papa bora pẹlu ijabu

Atẹjade kan ti alukoro fun ileesẹ ologun oriilẹ lorilẹede Naijiria fi sita lọjọ isẹgun, ni, asiri bi Shekau se n fi asọ iboju bori sa kiri tu si ọwọ awọn ologun, ti wọn tu gbogbo ibudo ikọ agbesunmọmi naa ka ni igbo nla Sambisa ati Camp Zero.

Awọn ologun ikọ Boko Haram tọwọ awọn ọmọ ogun Naijiria tẹ ni wọn jẹwọ wipe, igba ti nkan o sẹnure mọ fun isẹ laabi ikọ naa, pẹlu bi awọn ologun se rọ ojo ina sawọn ibuba awọn, lo faa ti Shekau fi da asọ ijabu awọn obinrin bori, to si di isansa ati alarinkiri bayii, lọna ati bọ mọ awọn ologun lọwọ.

Eeyan mẹrindinlaadọta to wa nigbekun Boko Haram lo gba idande

Ileesẹ ologun wa kede wipe, awọn ti tu gbogbo irinsẹ sita lati rii wipe ọwọ tẹ Shekau. Bakannaa lo fewe ọmọ mọ awọn araalu letilati sọra nipa Shekau to salọ yi, paapa awọn eeyan ipinlẹ Adamawa, Borno ati Yobe.

Lasiko tiwọn ologun Naijiria kọlu awọn ibuba ikọ adukukulaja Boko haram naa, awọn eeyan mẹrindinlaadọta ti ikọ naa mu gẹgẹbii onde, ni wọn tu silẹ ni ibuba Sabil Huda to wa ninu igbo nla Sambisa.

Related Topics