Ijamba: Ẹmi akẹkọ mọkanlelogun,olukọ meji bọ ni Kano

Ọkọ bọọsi akero to se ijamba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olukọ kan ati akẹkọ soso ni ori ko yọ ninu ijamba mọto naa

Awọn ọmọ ileewe girama mọkanlelogun ati olukọ meji ni wọn ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba mọto kan to waye lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹbi iroyin se sọ, awọn ọmọ ileewe yii atawọn olukọ wọn n rin irin ajo ifinimọlu lọ si ilu kano, lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria lati ilu Misau, to wa lagbegbe ila oorun ariwa orilẹede yi, nigba ti ijamba naa sẹlẹ.

Iroyin sọ wipe akẹkọ ati olukọ ileewe girama ilu Misau lawọn to lugbadi ijamba mọto naa.

Ajọ ẹsọ oju popo nipinlẹ Kano ati awọn alakoso ileewe girama naa salaye fun BBC wipe, isẹlẹ buruku yii sẹlẹ nigbati ọkọ bọọsi akero ti wọn wọ ati ọkọ nla kan kọlu ara wọn.

Oju ẹsẹ ni gbogbo awọn to wa ninu ijamba ọkọ naa ti gb'ẹmi mi.

Olukọ kan ati akẹkọ kansoso ni ori ko yọ ninu ijamba mọto naa.

Related Topics