Wole Soyinka: A ti f'aaye gba ipaniyan darandaran fun igba pipẹ

Wole Soyinka pelu Aare buhari Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Ojogbon Soyinka maa n s'ọrọ lori eto ilu loore-koore

Ọjọgbọn Wọle Soyinka ti sọrọ lori iwa ipaniyan awọn darandaran fulani ati awọn iṣẹ wọn jakejado orilẹ-ede Naijiria, nigbati o sọ pe orilẹ-ede naa ti f'aaye gba iwa ipaniyan ati ipanirun ti awọn darandaran nṣe fun igba pipẹ.

Ọjọgbọn naa tun beere fun pe ki minisita fun eto aabo ko ọrọ ti o sọ danu, eyi ti o n gbe agbara wọ awọn darandaran lati tẹsiwaju iwa ipaniyan.

Soyinka tẹsiwaju pe gbigba awọn darandaran yii laaye fun igba pipẹ ni ohun ti o fa bi iwa ipaniyan yii se waa peleke si lorilẹ-ede Naijiria bayii.

O sọ pe, "A ti gba iparun oko awọn agbẹ lọna ti eyikeyi iru agbegbe ti ọrọ ba kan ko lee f'arada mọ, eyi ti o si jẹ ohun meeriri fun ọpọlọpọ wọn.

"Ti a ko ba kọ ibi ara si nnkan bayi lati ibẹẹrẹ, ohun ni o maa n fa ki ipaniyan o peleke sii. A gbọdọ koju irufẹ iwa bayii lẹsẹkẹsẹ."

Nigbati o n gba awọn agbẹ ati awọn olori igberiko ni imọran lati daabobo ara wọn kuro lọwọ ipaniyan awọn darandaran, Soyinka sọ pe "ijafara lewu, ati pe awọn eniyan ko gbọdọ duro ki awọn darandaran gb'ẹmi wọn ki Naijiria to bẹrẹ iṣẹ lati dena ipaniyan bayi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọgbọn Wọle Soyinka bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ Buhari fun ipaniyan awọn fulani darandaran

Soyinka tun sọ wipe awọn ọmọ-ogun orilẹede Naijiria ni lati mu awọn alamojuto eto aabo ṣinṣin ati pe wọn gbọdọ daabo bo ẹmi awọn ara ilu ati dukia wọn pẹlu.

Ọpọ asise to kun inu ijọba Buhari lo jẹ afọwọfa

Soyinka wa mẹnuba igbesẹ bi Buhari se pe akọwe apapọ fun ajọ to nse amojuto eto adojutofo nidi ilera (NHIS), Usman Yusuff pada sẹnu isẹ, lẹyin ti minisita feto ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewọle ni ko lọ rọọkun nile na nitoripe o se owo ilu basubasu, gẹgẹ bii apẹrẹ kan to n safihan pe oniruuuru asise afọwọfa lo kun inu isejọba Buhari dẹnu.

Sugbọn awọn agbẹnusọ fun aarẹ Buhari ko tii fesi pada lori ọrọ yi. A o maa mu esi wọn wa fun yin ni kete ti wọn ba ti fesi.

Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati ba awọn agbẹnusọ fun aarẹ Buhari s'ọrọ ja si pabo.