2019: Awọn sẹnatọ to n fẹ Buhari binu nitori atunto ibo

Senatọ Bukọla Saraki Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilẹ ti ta si ti aigbọraẹniye ti n waye laarin ẹka alasẹ ati awọn asofin lorilẹede Naijiria

Awọn asofin mẹwa to n satilẹyin fun aarẹ orilede Naijiria, Muhammadu Buhari ti binu jade nibi ijoko ile asofin agba lọjọọru lati fi ẹhonu wọn han lori bi ile asofin agba se tẹwọgba abọ igbimọ alajumọse laarin ile asofin agba ati tawọn asoju-sofin lori atunse ofin idibo.

Awọn asofin naa, lai naani pe ile ti tẹwọgba abọ igbimọ ọhun ni, awọn yoo ri daju pe ile pa ohunda lori ipinnu rẹ yi.

Wọn ni afojusun atunse ofin idibo naa ni wọn se nitori aarẹ Muhammadu Buhari.

Aarẹ ile asofin agba, dokita Bukọla Saraki lo kesi awọn asofin lati dibo lori abọ naa, lati mọ boya wọn faramọ tabi wọn ko faramọ, lẹyin ti alaga igbimọ ọhun, Sẹnatọ Sulaiman Nazif, ti gbe abọ igbimọ rẹ kalẹ tan.

Ohun ti awọn asofin naa n binu le lori.

Awọn asofin to n binu ni atunse ofin idibo ọhun n na ika atako si Aarẹ Muhammadu Buhari.

Awọn asofin to dibo pe awọn faramọ abọ naa pọ ju awọn to dibo pe awọn ko faramọ lọ, ti aarẹ ile si fontẹ lu abọ ọhun, eyi to mu ki ariwo sọ.

Bakannaa ni Bukọla Saraki tun kọ lati gba awọn asofin to nawọ soke lati sọrọ tako idibo ọhun laaye lati wi tẹnu wọn.

Related Topics