2019: INEC ni awọn ọga agba tuntun

Gbagede ile igbimọ asofin agba orilẹede Naijiria Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Lẹyin ọpọlọpọ iforigbari, ile asofin agba buwọlu awọn orukọ ọga agba tuntun fajọ INEC

Awọn asofin apapọ orilẹede Naijiria ti buwọlu orukọ awọn ọga agba tuntun fun ajọ eleto idibo orilẹede naa.

Awọn oga agba tuntun fun ajọ INEC ti wọn buwọlu orukọ wọn ni, Baba Abba Yusuf (Borno), Dr. Uthman Abdulrahman Ajidagba (Kwara), Mr. Segun Agbaje (Ekiti), Dr. Cyril Omorogbe (Edo), Yahaya Bello (Nasarawa), Dr. Emmanuel Alex Hart (Rivers), Mohammed Mogaji Ibrahim (Gombe).

Awọn asofin agba orilẹede Naijiria buwọlu orukọ wọn lọjọbọ lẹyin ti igbimọ tẹẹkoto to n mojuto ọrọ ajọ INEC nile asofin agba ti se ayẹwo lori awọn orukọ naa.

Bi a ko ba ni gbagbe, nibẹrẹ ọdun 2017 ni awọn asofin agba orilẹede Naijiria tẹsẹ bọ sokoto kannaa pẹlu ileesẹ aarẹ lori bo se kuna lati yọ olori ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ lorilẹede yi, EFCC, Ibrahim Magu, ẹni tawọn asofin ti kọkọ wọgile orukọ rẹ gẹgẹbi alaga ajọ EFCC nitoripe gẹgẹbi iwoye ati iwadi wọn, Magu ko kunju iwọn lati lewaju ajọ to se pataki bii EFCC.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Eeyan mẹsan nile asofin agba kede orukọ wọn gẹgẹbii ọga agba tuntun fajọ INEC

Ọjọ pẹ ti awuyewuye ti n waye lori iyansipo awọn ọga agba tuntun fajọ INEC

Sugbọn ileesẹ aarẹ orilẹede Naijiria kọ jalẹ wipe afori afọrun, Magu n lawọn fẹ nipo ọhun eyi ti ko dun mọ awọn asofin agba nin, ti wọn ni bi adiyẹ da mi loogun nu, maa fọ lẹyin lawọn yoo fi ọrọ naa se.

Wọn tun fi kun pe bi ileesẹ aarẹ ba faake kọri lori ọrọ naa, awọn pẹlu ko ni buwọlu awọn orukọ awọn ọmọ igbimọ lajọlajọ gbogbo tileesẹ aarẹ ba mu tọọ wọn wa, bẹrẹ pẹlu orukọ awọn ti wọn fẹ yan sipo lọgalọga lẹnu isẹ ajọ eleto idibo apapọ orilẹede Naijiria.

Loju opo Twitter rẹ, aarẹ ile asofin agba Bukọla Saraki ni oun nireti pe igbesẹ ile asofin agba naa yoo seranwọ lati ko ipa si ifsẹmulẹ eto idibo to mọyan lori jakejado orilẹede Naijiria.

Related Topics