Ọlọpa: Falana fun ọlọpa lọjọ meje lati gbe iwadi ipaniyan sita

Awọn ọlọpa Naijiria ninu ọkọ nla Image copyright Getty AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọ iwadi ipaniyan tileesẹ Ọlọpa Naijiria se ni ko ni abọ

Amofin agba kan lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Fẹmi Falana, ti fun ọga agba ọlọpa ati ileesẹ ọlọpa lorilẹede yi, ni gbedeke ọjọ meje lati se agbekalẹ awọn abajade iwadi lọlọkan-o-jọkan ti wọn ti se, lori awọn isẹlẹ ipaniyan to ti waye sẹyin lorilẹede wa.

Ninu iwe kan to kọ sileesẹ ọlọpa lọjọọru ni amofin Fẹmi Falana ti sọ eyi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn apaniyan lorilẹede Naijiria ni ko jiya ẹsẹ wọn nitori aisi ẹri to daju.

Amofin agba naa ni, bi orilẹede Naijiria ba fẹ wa egbo dẹkun si gulegule isẹlẹ ipaniyan to n waye, ko si lee tete mu ki ijẹjọ awọn afunrasi o ya kiakia, ileesẹ ọlọpa ni lati ko awọn abọ iwadi gbogbo to ti se si awọn isẹlẹ ipaniyan to ti waye sẹyin sita gbangba, papaa julọ laarin ọdun 2011 si asiko yii.

  • Isekupa awọn ọlọpa marundinlọgọta ati awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS mẹwa lọdun 2013 nipinlẹ Adamawa.
  • Iku awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun meji nipasẹ wahala laarin awọn darandaran Fulani ati agbẹ olohun ọsin nipinlẹ Benue laarin ọdun 2013 si 2016.
  • Iku ẹgbẹrin Fulani ti awọn ẹgbẹ agbebọn pa ni agbegbe Mambila nipinlẹ Taraba losu kẹsan ọdun 2017.
  • Iku eeyan mẹrinlelugba tawọn agbebọn pa lagbegbe guusu Kaduna losu kejila ọdun 2015.
  • Isẹlẹ isinku idakọnkọ tawọn ologun se fun ojilelọọdunrun o le meje awọn ọmọ ijọ shiites nilu Zaria to wa nipinlẹ Kaduna.
  • Iku aadọjọ awọn ajijagbara Biafra latọwọ awọn osisẹ alaabo lẹkun ila oorun guusu orilẹede Naijiria laarin ọdun 2013 ati 2017.
  • Awọn mẹrindinlaadọta miran ti wọn pa nipinlẹ Enugu losu kẹrin ọdun 2016.

Awọn isẹlẹ ipaniyan ti Falana tọkasi.

Agba amofin naa ko sai tun yannana ọkan-o-jọkan awọn ipaniyan to ti waye, bii bawọn ọmọ ẹgbẹ okunokun Ombatse se pa awọn ọlọpa marundinlọgọta ati awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS mẹwa lọdun 2013 nipinlẹ Adamawa.

Bakanaa lo mẹnuba iku awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun meji ti wọn ti gbẹmi mi lati ipasẹ wahala laarin awọn darandaran Fulani ati agbẹ olohun ọsin nipinlẹ Benue laarin ọdun 2013 si 2016.

Bẹẹ ni ko tun gbagbe awọn ẹgbẹrin Fulani tawọn ẹgbẹ agbebọn kaakiri ti pa lagbegbe Mambila nipinlẹ Taraba losu kẹsan ọdun 2017 eleyi ti Emir tilu Kano, Alhaji Sanusi Lamido Sanusi ni awọn akọroyin ko gbe sita.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ ipe araalu sawọn ileesẹ ijọba lati gbe awọn aabọ kan jade sita ko so eso rere saaju asiko yii lorilẹede Naijiria.

Nigba to ba ileesẹ BBC Yoruba sọrọ, amofin Falana ni,

'idi toun fi kọ lẹta si ọga ọlọpa Naijiria ni lati kan an nipa fun gẹgẹbi ofin orilẹede Naijiria ti se laa kalẹ p,e ko fi abọ iwadi wọn sita fun wa lati ri, ka le e fi sọwọ sawọn amofin agba lawọn ipinlẹ tọrọ kan fun igbesẹ to tọ.'

O ni bi ileesẹ ọlọpa ba kuna lati gbe iwe abọ iwadi yii jade, ileẹjọ lawọn yoo gbalọ lati fi agbara ofin muu.

Related Topics