Awọn asofin ni k'ijọba apapọ o dawọ owo ori ọja lati okeere duro

Awọn agolo ikọja si ni ibudokọ ojuomi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn asofin agba orilẹede Naijiria ni afikun owo ori ọja to n wọle lati ilẹ okeere n se akoba idagbasoke

Ile asofin agba orilẹede Naijiria ti ke si ijọba apapọ lati so ọwọ rẹ kọ lori igbesẹ afikun owo ori ọja to n wọle lati ilẹ okeere.

Aarẹ ileegbimọ asofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki tun pasẹ fun igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ eto ọgbin, eto iṣuna ati ileesẹ asọbode lati lọ jumọ joko pọ pẹlu ileesẹ eto iṣuna ijọba apapọ lori ọna ati se agbeyẹwo owo ori ọja to nwọle lati ilẹ okeere.

Asẹ yii waye lẹyin ti asofin agba kan, Sẹnatọ Sabo Mohammed ti pe akiyesi awọn asofin agba si ọrọ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹka eto ọgbin wa lara awọn ẹka ti afikun owo ori ọja to n wọle lati ilẹ okeere n se akoba fun

Bakanaa ni ileegbimọ asofin agba orilẹede Naijiria tun pasẹ awọn igbimọ ti ọrọ kan naa lati ransẹ pe gbogbo awọn ileesẹ ijọba, lajọlajọ ati awọn alẹnulọrọ to wa lẹka ọrọ owo ori lori ọja okeere lati se iwadi si ọrọ naa ki wọn si wa ojuutu si afikun owo ori ẹru to n wọ orilẹede Naijiria lati okeere.

Nigba to n gbe lori akiyesi naa, aarẹ ile asofin agba orilẹede Naijiria ni" Ọrọ se pataki pupọ bẹẹni gbogbo kudiẹ-kudiẹ to n waye lori awọn ofin ati igbesẹ ijọba gbogbo wọnyii nilo amojuto. Koko ohun to f'arahan ninu ọrọ yii paapaa ti a ba n sọrọ eto ọgbin ni wi pe o yẹ ki a pese aye ti yoo le gba awọn to n sisẹ ni ẹka naa duro daadaa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹkunwo lori ọja kun ara abajade afikun owo ori ọja to n wẹle sorilẹede Naijiria, gẹgẹbi awọn asofin se sọ

Awọn asofin naa kọminu lori ohun ti wọn pe ni igbesẹ awọn ileesẹ ati lajọlajọ ijọba kan lorilẹede Naijiria lati maa gbe awọn igbesẹ ti yoo ko ifasẹyin ba idagbasoke eto ọrọ aje orileede naa.

Aarẹ ile asofin agba, Sẹnatọ Saraki wa fun awọn ileesẹ ati lajọlajọ ti ọrọ kan ni ọsẹ kan lati fi se atunse gbogbo to ba yẹ bi bẹẹkọ, o ni awọn asofin agba yoo gbe awọn igbesẹ ti ofin la kalẹ fun un lati gbe.