PDP: Buhari ni ifẹyin tọ si julọ ni Naijiria bayii

Aarẹ Muhammadu Buhari, Oloye Bisi Akande Akande ati Asiwaju Bọla Tinubu n sọrọ Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ipade laarin Tinubu, Akande ati Buhari ti fa oniruuru awuyewuye lẹsẹ

Ẹgbẹ oselu PDP ti ransẹ si asiwaju ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu wipe amọran to gba Oloye Ọbasanjọ ati Ọgagun-fẹyinti Ibrahim Babangida ko yẹ ko mọ bẹẹ afi ko tun fi to Aarẹ Buhari gan pẹlu pe asiko ile too lọ fun.

Ninu atẹjade kan ni ẹgbẹ oselu PDP ti sọrọ yii.

Ni ọjọ isẹgun ni Asiwaju Bọla Tinubu pẹlu oloye Bisi Akande lọ ree se ipade idankọnkọ pẹlu Aarẹ Buhari lẹyin eyi to fi to awọn oniroyin leti wipe asiko to fun Ọbasanjọ ati IBB lati se gaya fun oselu.

Àkọlé àwòrán Oloye Ọbasanjọ lo kọkọ side ipe 'lọ ree fẹyinti'fun Aarẹ Buhari

Ninu atẹjade rẹ eleyi ti oludari eto ipolongo fun ẹgbẹ oselu PDP lapapọ, Kọla Ologbodiyan fi sita, o ni ọrọ ti Tinubu sọ dabi ti ajẹ ke lana, ọmọ ku loni ni pẹlu ohun ti oloye Olusẹgun Ọbasanjọ ati Ibrahim Babangida, ẹgbẹ oselu PDP ati omilẹgbẹ awọn ọmọ orilẹede Naijiria sọ wipe ile too lọ fun Aarẹ Buhari lẹyin to ba pari saa rẹ ni ọdun 2019.

"Asiwaju Tinubu funrarẹ mọ wipe Aarẹ Buhari gan an lo tọ si ju laarin awọn agbaagba majẹobajẹ to wa lorilẹede yi bayii lati se gaya fun oselu ki wọn lọ fẹyinti lati lee yọ orilẹede yii kuro ninu ofin isejọba to kun fun wahala ọrọ aje itajẹsilẹ loniraa-an-ran ati iwa kotọ gbogbo."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lẹta ipe ti Ibrahim Babangida kọ fa oniruru wahala silẹ laarin agbẹnusọ rẹ ati awọn agbofinro

Oniruru ipe ati arọwa lo ti n jade si Aarẹ Buhari ti orilẹede Naijiria lẹnu lọwọlọwọ yii wipe ko sun sẹyin fun oselu lẹyin to ba ti pari saa isejọba to n lo lọwọ yii ni ọdun 2019.

Pataki ninu awọn eniyan wọnyi ni Aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri Olusẹgun Ọbasanjọ, Aarẹ ologun tẹlẹ Ọgagunfẹyinti Ibrahim Babangida pẹlu ogbontagi onkọwe e ni, Ọjọgbọn Wọle Soyinka.