Idije Champions League: Ronaldo tan bi oorun ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu PSG

Ronaldo ati awọn agbabọọlu miran lori papa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ode dun fun ikọ agbabọọlu Real Madrid ninu ipele Komẹsẹ-o-yọọ akọkọ nibi idije agbarijọpọ ọgbọ agbabọọlu ti champions league ni ilẹ Yuroopu

Ode dun fun ikọ agbabọọlu Real Madrid ninu ipele Komẹsẹ-o-yọọ akọkọ nibi idije agbarijọpọ ọgbọ agbabọọlu ti champions league ni ilẹ Yuroopu.

Ami ayo mẹta si ẹyọkan ni Real Madrid fi gbẹyẹ mọ PSG lọwọ ni papa isire Bernabau ni orilẹede Spain.

Bi o tilẹ je wi pe ekuru fẹ gbẹyin ni ifanfan fun ikọ Real Madrid pẹlu bi Adrien Rabiot lati ikọ PSG se kọkọ gba ayo kan wọle ni opin abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ wọn naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹnu ti n kun awọn agbabọọlu Real Madrid fun bi ijafafa wọn se n mẹhẹ lori papa

Sugbọn ko pẹ kojinna ti ogbontagi agbabọọlu jẹun ni, Cristiano Ronald gba bọọlu meji wọle ni sisẹ n tẹle ki Marcelo to ka are gbogbo nilẹ.

Ayo akọkọ, oni gbee lẹ koo gba si amule, iyẹn penalty ti Ronaldo gba wọle lo mu ki agbabọọlu ọhun di agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ayo ọgọrun wọle fun ẹgbẹ agbabọọlu kan naa ninu iwe itan idije Champions league.

Ni saa idije bọọlu to to kọja ni ikọ agbabọọlu Real Madrid kọ iwe itan tuntun gẹgẹbi ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ champions league ilẹ Yuroopu ni tẹle-n-tẹle.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nkan o senuure fun Neymar ati awọn akẹgbẹ rẹ ni PSG

Amọsa, nkan o se ẹnuure fun ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ni saa yii nitori lọwọ yii, ipo kẹrin ni wọn wa ninu idije liigi orilẹede Spain; bẹẹni wọn ti yọ ọwọ wọn lawo ninu idije ife ẹyẹ Copa del Rey lorilẹede Spain.

Ni ọjọ kẹfa osu kẹta ni wọn yoo tẹ ọkọ leti lọ si papa isire Parc des Princes ni orilẹede france fun igun keji ifẹsẹwọnsẹ wọn.

Related Topics