Cyril Ramaphosa, aarẹ tuntun fun orilẹede South Africa?

Cyril Ramaphosa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin ọpọlọpọ irinajo, Cyril Ramaphosa yoo di aarẹ̀ orilẹ̀ede South

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye, ọgbẹni Jacob Zuma fi ipo aarẹ orilẹede South Africa silẹ ni alẹ ọjọọbọ.

Ireti ọpọ onwoye ni wipe, ọgbẹni Cyril Ramaphosa to jẹ alaga ẹgbẹ to n sejọba lorilẹede South Africa, ANC ni yoo bọ si ipo naa.

Ni ọdun 2017 ni Cyril Ramaphosadi alaga ẹgbẹ oselu ANC lasiko yii gan ni o dabi ẹni wipe edeaiyede bẹrẹ laarin oun ati ọgbẹni Zuma pẹlu bi Zuma se fẹ fi iyawo rẹ, Nkosazana Dlamini-Zuma, jẹ alaga ẹgbẹ oselu naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ ọmọ orilẹede South Africa lo ti n reti ikọwe fi ipo silẹ Jacob Zuma

Pẹlu bi ọgbẹni Jacob Zuma se kọwe fipo silẹ, Cyril Ramaphosani adele aarẹ titi ti ile asofin apapọ orilẹede SouthAfrica yoo fi buwọlu u gẹgẹbi aarẹ.

Amofin ni Cyril Ramaphosa ki o to di ọmọ ileegbimọ asofin to si ko ipa ribiribi ninu kikọ iwe ofin orilẹede South Africa lẹyin igbominira lọwọ awọn alawọ funfun.

Bakanaa lo ko ipa to loorin gẹgẹbii asiwaju ninu ilana iduna-dura eyi to fi opin si isejọba awọn alawọ funfun lorilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Jacob Zuma fi ipo aarẹ orilẹede South Africa silẹ lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye

Oloselu to fa isẹ isowo dani ni Cyril Ramaphosa; o si wa lara awọn oloselu to lowo julọ lorilẹede naa.

Ọpọlọpọ awọnalatako rẹ lo n se akawe rẹ gẹgẹbi ẹni to lo anfani rẹ pẹlu oselu lati fi gbe ileesẹ isowoo rẹ soke.

Oniruru ẹsun bii ipaniyan nwọn ti fi kan an saaju asiko yii sugbọn ileejọ ni ko jẹbi ẹsun yii bi o ti l ẹ jẹ wipe olori ẹgbẹ oselu Economic Freedom Fighters, Julius Malema ni oun ri Ramaphosa gẹgẹbi ẹni ti yoo maa ta awọn eeyan rẹ lọpọ fun awọn onisowo lati ilẹ okeere atawọn atọhunrinwa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ifigagbaga fun ipo alaga gb oselu ANC kun ara ohun to fa ipinya laarin Ramaphosa ati Zuma

Ni ọdun 1952 ni wọn bii ni Soweto ni ilu Johanesborg ki o to di wipe wọn fi si atimọle laarin ọdun 1974 sin ọdun 1976 fun oniruru ẹsun diditẹ mọ ijọba alawọ funfun.

Julius Malema lo da ẹgbẹ awọn osisẹ awakusa silẹ lọdun 1982 ki o to di ọmọ ileegbimọ asofin lorilẹede South Africa, laipẹ lo si di alaga igbimọ to se aayan atunto iwe ofin orilẹede naa lọdun 1994.

Ni ọdun 1997 lo kan lu agbami oowo sise.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn oluwọde n pe fun ifiposilẹ Jacob Zuma

Ni ọdun 2014 lo di igbakeji aarẹ orilẹede South Africa ki wọn to dibo yan an si ipo alaga apapọ ẹgbẹ oselu ANC lọdun 2017.

Eto idibo si ipo alaga ẹgbẹ oselu yii gan lo fa dukuu laarin Cyril Ramaphosa ati Jacob Zuma.

Lasiko ti aarẹ Zuma fi n koju ipenija ẹsun ifipabanilopọ ti obinrin kan fi kan nigba naa, ọgbẹni Ramaphosa sọ yanyan wipe oun gba obinrin to fi ẹsun ifipabanilopọ kan Zuma gbọ.