Akinyẹmi: Ọgbun mẹrin to wa niwaju aarẹ tuntun ni South Africa

Cyril Ramaphosa n nu oju rẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Omi n laamu fun Cyril Ramaphosa

Pẹlu bi ọgbẹni Jacob Zuma ti se kọwe fi ipo rẹ siẹ bayii, ibeere lẹnu ọpọlọpọ lorilẹede SouthAfrica ati kaakiri agbaye ni wipe, ki lo kan bayii nibẹ?

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, ọjọgbọn ninu imọ nipa ajọsepọ orilẹede si orilẹede,Bọlaji Akinyẹmi ni omi n bẹ laamu fun orilẹede South Africa lẹyin ikọwefiposilẹ Zuma.

Ọjọgbọn Akinyẹmi ni lootọ ọpọ awọn eeyan lo ni ireti to ga nipa isejọba to n bọ lọna eleyi ti yoo wa labẹ isakoso ọgbẹni Cyril Ramaphosasugbọn awọn ọgbun mẹta kan wa lọna rẹ ti o gbọdọ sọra fun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Isoro ipese isẹ fun awọn ọdọ kun ara ipeniuja iwaju aarẹ tuntun ni orilẹede South Africa

Awọn ọgbun mẹrin naa.

Ọgbun akọkọ ni ipinya ati aisi isọkan to wa laarin ẹgbẹ oselu ANC lorilẹede South Africa lọwọ yii.

"Ti a ba wo o daadaa, iwọnba perete ibo ni Cyril Ramaphosa fi bori nibi idibo si ipo alaga ẹgbẹ oselu naa to waye ni ọdun 2017. Ibeere nla to wa nibẹ bayii ni wipe, se yoo lee mu isọkan ba awọn igun gbogbo to n suyọ nibẹ"

Ọbun keji ti Ọjọgbọn Bọlaji Akinyẹmi tun salaye ni ẹhonu awọn lookọ lookọ ati alagbara ti wọn fi ẹsun kan pe wọn lẹdi apo pọ mọ Jacob Zuma lori ẹsun iwa ijẹkujẹ ati ibajẹ ti wọn fi kan an.

Ibeere ti Ọjọgbọn Akinyẹmi beere lori eyi ni wipe, njẹ Cyril Ramaphosayoo lee tan ẹhonu awọn alagbra wọnyii bi ti wọn ko si ni daa ni agbo si ina?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awuyewuye lori ọrọ Zuma yoo se ọ̀pọ̀ ijamba fun ẹgbẹ oselu ANC

Ẹkẹẹta ninu awọn ọgbun ti minisita fun ọrọ ilẹ okeere nigbakanri lorilẹede Naijiria tun mu ẹnu le ni ti ẹsun iwa kotọ eleyi ti wọn n fi kan Cyril Ramaphosa funrarẹ. O ni bi aarẹ tuntun to fẹ wọle ni orilẹede South Africa ba ti se lee mojuto ọrọ yii to yoo sọ bi isejọba rẹ yoo ti ri.

"Lootọ a ko lee ri angẹli ni ipo isejọba nitori gbogbo awọn olori orilẹede kaakiri agbaye naa lo ni tiwọn lọwọ nitori ibi gbogbo la n dana alẹ, ọbẹ kan dun ju ara wọn lọ ni."

Ogbun kẹrin ti o salaye fun BBC Yoruba ni ọgbun ipa ti awuyewuye to ba ọrọ ati fi iposilẹ Jacob Zuba lọ yoo ni lori eto ọrọ aje orilẹede naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ohun ti ọjọ ọla ni fun awọn ọdọ ni orilẹede South Africa ko tii daju

Lọwọ ti a n sọrọ yii, ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun awọn ọdọ orilẹede South Africa ni airisẹ n ba finra. Eyi si jẹ ohun ti ko dara to fun orilẹede bii South Africa. Isẹ nla ni aarẹ tuntun yoo se ki wahala to suyọ lasiko ifiposilẹ aarẹ ana lorilẹede naa o maa baa di majẹle fun ọrọ aje rẹ

Ẹkọ fun ẹgbẹ oselu lorilẹede Naijiria.

Ọjọgbọn Bọlaji Akinyẹmi wa yannana rẹ fun awọn isejọba orilẹede Naijiria wipe ni ẹkọ nla ni orilẹede Naijiria ni lati kọ, paapaajulọ lati rii wipe ẹgbẹ oselu lagbara ju awọn oloselu lọ.

O ni o jẹ ohun to bani ninu jẹ pupọ wipe ọna ti oselu n gba lorilẹede Naijiria n fun awọn oloselu laaye lati da ẹgbẹ oselu silẹ ki wọn si maa se akoso rẹ bi o ba se wu wọn, eleyi ti ko ri bẹẹ ni orilẹede South Africa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bawo ni aje yoo se ri fun ni South Africa

"Nibẹ ijijagbara fun ominira lo bi awọn ẹgbẹ oselu, ko si si bi oloselu se lee pe ara rẹ ni nkan lai lọwọ ẹgbẹ oselu ninu.

O wa gba awọn awọn ọmọ ẹgbẹ ANC nimọran lati sọọse ki omi maa baa tẹyin wọ igbin wọn lẹnu.