Femi Falana: Isọkusọ ni awọn ologun n sọ lori Shekau

Ileesẹ ọmọogun orilẹede Naijiria

Iko ọlọpa orilẹede Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fẹmi Falana soro lori Abubakar Shekau

Amofin agba kan lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Fẹmi Falana ni isọkusọ patapata gbaa ni iroyin to ti ọdọ ileesẹ ọmọogun orilẹede Naijiria jade pe awọn n wa olori ikọ agbesunmọmi Boko Haram, Abubakar Shekau a ti pe o mu ra bi obinrin lati sa asala kuro ni igbo nla sambisa lọjọ isẹgun.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Amofin Falana ni ọrọ ti ko see maa gbọ seti ni bi ileesẹ ọmọogun se n fi igbagbogbo ke ibosi sita wipe awọn ti fẹẹ mu ọgbẹni Shekau.

Gbogbo ohun ti wọn n sọ yii, isọkusọ patapata ni. Yoo ti fẹẹ to igba mẹwa ti wọn ti kede pe awọn mu arakunrin yii.

Arakunrin ti a n sọ yii a ti fẹẹ ku to igba mẹwa ti awọn ologun n sọ fun wa pe awọn ti pa. Eleyii, wọn ni o wọ asọ obinrin lati sa lọ, nigba ti ẹ rii to n salọ, ki lẹ se fun? Ẹ o se da ibọn bo o?

Image copyright Getty Images

Amofin agba naa to tun jẹ odu ajafẹtọ araalu ni bi awọn ologun ba sọ wipe awọn mọ ibi ti olori ikọ adunkukulajamọni naa n kọri, o yẹ ki wọn ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lori awọn eto abo to tọ ati sna lati mu apanijaye ọkunrin naa dipo pipariwo sigboro.

Bakanna lo tun salaye wipe ijọba lo lẹbi bi ikọlu ipaniyan se n waye lorilẹede Naijiria.

Amofin agba Falana ni 'ko si ilu lagbaye ti wọn kii tii paniyan sugbsn toripe a kii gbe wọn lọ sile ẹjọ ni ilu wa, lo faa ka maa paniyan, boya wọn n dibo ni o, boya darandaran ni o, wọn rii pe ko si nkan to se awọn to see saju. Eyi lo si faa ti awa pllu fi n sọ wipe o to gẹẹ.'