Ibi gbogbo la n kadiyẹ alẹ, 'ekute jẹ idi ogun oloro lagọ ọlọpa' ni Kenya

Ọkẹẹrẹ n jẹ nkan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Isẹlẹ yii n waye lẹyin ti ọkan lara awọn osisẹ ajọ to n se idanwo si ile ẹkọ giga fasiti ni Naijiria, JAMB ti kede faye gbọ pe ejo mi miliọnu mẹrindinlogoji Naira

Awọn ọlọpa kan lorilẹede Kenya ti sọ fun ileẹjọ kan wilu Kwale wipe awọn ẹru ofin to poora ni ibi ti wọn ko si ni agọ ọlọpa wọn ko sa dede poora bikose awọn eku adugbo to ko wọn jẹ tan pata.

Ọrọ yii n waye nigbati awọn ọlọpa mẹta kan to n jẹri fun olupẹjọ ninu ẹjọ ti wọn pe awọn obinrin mẹrin kan ti wọn fi ẹsun kan pe wọn n ko ẹẹdẹgbẹsan o le mẹwa idi ewe oogun oloro igbo ti wọn n pe ni 'Bhang' lọna ti ko ba ofin mu lati ilu Migori si Ukunda ni Kwale.

Awọn ọlọpa mẹta ọhun ni Ken Olonde, Patrick Baya ati Sajẹnti Hamisi Kombo ti wọn fi ofin mu awọn afunrasi obinrin naa.

Bi a ko ba ni gbagbe, ni orilẹede Naijiria laipẹ yii, ọkan lara awọn osisẹ ajọ to n se idanwo si ile ẹkọ giga fasiti nibẹ, JAMB ti kede faye gbọ pe ejo mi miliọnu mẹrindinlogoji Naira owo ajọ JAMB to wa ni ipamọ ọfiisi naa ni ipinlẹ Benue lorilẹede Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O fẹ jọ bi ẹnipe awọn ẹranko ni awọn eeyan n fi ẹsun kọ lọrun bayii

Nigba ti o n fi ọrọ wa wọn lẹnuwo, agbẹjọro fun ọkan lara awọn olujẹjọ naa, Abdul Aminga ke si awọn ọlọpa naa lati salaye ohun to sokunfa bi awọn idi oogun oloro naa se dinku si ẹẹdẹgbẹsan o le mẹwa.

Awọn ọlọpa naa ni eku lo ya bo agọ ọlọpa awọn to si jẹ awọn idi ewe oogun oloro naa ti wọn n pe ni 'Bhang'

Amọsa, kayefi ọrọ naa ni wipe eku to jẹ idi oogun oloro to wa ninu apoti ko da iho lu tabi jẹ ibikibi lara apoti ti wọn ko o si.

Bakanna ni wọn tun sọọ ko awọn ọlọpa naa loju pe ọtọ ni iye owo ti wọn n ta egboogi oloro naa nigboro, ọtọ ni iye ti awọn ọlọpa yii kọ silẹ sinu iwe ofin ni agọ wọn.

Ni ọjọ kẹrinlelogun osu keje ọdun 2017 ni ọwọ awọn ọlọpa tẹ awọn afunrasi naa ti orukọ wọn njẹ Pauline Moraa, Elizabeth Atieno, Nancy Auma ati Mercy Achieng nitosi ileto kan ti orukọ rẹ n jẹ Banga lagbegbe Mbunguni.

Related Topics