Ẹgbẹrun meji o le lawọn to n reti iku lọgba ẹwọn Naijiria

Awọn eeyan duro si ẹnu ọna abawọle si ọ̀gba ẹwọn kan lorilẹede NAijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ awọn ti wọn da ẹjọ iku fun ni awọn gomina kuna lati buwọlu iwe iku wọn

Ẹgbẹrun meji ati ọrinlelugba o le ẹyọkan awọn ẹlẹwọn ti wọn ti gba idajọ iku ni wọn kaakiri awọn ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria lọwọ yii sugbọn ti awọn gomina kọ lati fi ọwọ si iwe iku wọn.

Ọgaagba ileesẹ ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria, Ahmed Ja'afaru sọ pe eleyi kun ara ohun to n sokunfa akunfọ ati akunfaya ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria.

Jafaru to sọrọ niwaju ijoko itagbangba ti ile asofin agba n se lori igbesẹ lati dẹkun akunfọ ati akunfaya ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Àkọlé àwòrán,

aisi ifọkansin to loorin lati ọdọ ijọba gbogbo kun ara isoro ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria

Ọga agba ileesẹ ọgba ẹwọn naa ni pẹlu bi ọda owo awo olokun se n ba ileesẹ ọgba ẹwọn orilẹede Naijiria finra to, ileesẹ naa n gbe igbesẹ lati mu igba ọtun ba awọn ẹlẹwọn rẹ gbogbo.

O ni lara igbesẹ to lamilaaka ti wọn gbe ni ti irinwo ati ọgbọn awọn ẹlẹwọn ti wọn kẹkọgboye imọ ijinlẹ nileẹkọ giga fasiti agbele-gboye National Open University.

Awọn asofin agba lorilẹede Naijiria n se agbeyẹwo awọn ofin to rọ amojuto ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Irinwo ati ọgbọn awọn ẹlẹwọn ti wọn kẹkọgboye imọ ijinlẹ nileẹkọ giga fasiti agbele-gboye National Open University.

Nibi ijoko itagbangba ti wọn se naa, lara ohun ti awọn yọ sita gẹgẹbi ohun to n fa ifasẹyin ba ipo ti awọn ọgba ẹwọn wa naa ni aisi ifọkansin to loorin lati ọdọ ijọba gbogbo, aisi isuna to kun oju iwọn.

Ninu ọrọ rẹ nibi ijoko itagbangba naa, sẹnatọ Olurẹmi Tinubu pe fun idaduro awọn ọgba ẹwọn fun awọn obinrin eleyi to ni o ni lati jina gedengbe si ti awọn ọkunrin.

Alaga igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ abẹle nile asofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnatọ Andy Uba tẹnumọ bi o se se pataki fun awọn lajọlajọ ijọba lati maa jihin abajade iroyin gbogbo nipa ileesẹ ati ajọ wọn fun ayẹwo ati igbesẹ to tọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ẹlẹwọn ni ko ni ireti lẹyin ti wọn ba kuro lọgba ẹwọn

Nigba ti o nsọrọ lori akoko to lo ninu ọkan lara awọn ọgba ẹwọn lorilẹede Naijria, ọkan ninu awọn asofin naa, Sẹnatọ Shehu Sani ni ohun ti oju oun ri lẹwọn ko see maa fi ẹnu sọ.

Sẹnatọ Sani ni ko yẹ ko jẹ ori ileesẹ ọgba ẹwọn ni wọn yoo maa di ẹru igbesẹ gba-maa-binu ti wọn yoo maa san fun awọn ẹlẹwọn le.

Ohun ti awọn asofin agba miran tun sọ

Sẹnatọ Clifford Ordia.

"Ojuti nla nla ni ipo ti awọn ọgba ẹwọn lorilẹede yii wa bayii. Asiko ti to fun idasilẹ ajọ ti yoo maa se amojuto ọgba ẹwọn ki wọn lee tubọ gba muse sii ju bi wọn se wa bayii."

Sẹnatọ Bayero Nafada.

"Olori isoro ileesẹ yii ni ọda owo. Bi a ba buwọlu abadofin yii tan, yoo tun pa kun wahala inawo ni, a o nilo alekun aabo, bawo la se fẹ yanju eleyi?"

Sẹnatọ Andy Ubah

"Fun ẹni to lo ọdun mẹwa lọgba ẹwsn, to wa buse gede, tẹẹ ni irọ ni wọn pa mọọ lẹyin ọdun mẹwa, arọwa wo tabi ẹbun gba maa binu wo lẹ lee se fun. Se yoo kan maa lọ bẹẹ naa ni."