Ọti lile ko ni anfaani f‘ara

Awọn ọti lile to wa lori atẹ fun tita
Àkọlé àwòrán,

Oniruuru ijamba ni awọn ọti pẹlẹbẹ ati tinu ike yi ti se fun ara ọpọ eeyan.

O ti di asa lorilẹede Naijiria lati maa ri oniruuru ọti lile ti wọn yoo patẹ lẹba oju popo laibikita.

Awọn ọti lile yi, si ni wọn ti sọ ni orisirisi orukọ bii pẹlẹbẹ, rubutu ati gbọọrọ

Oniruuru ileesẹ si lo nse awọn ọti lile yi sita, ti wọn si sọ wọn ni orisirisi orukọ bii Karaole, origin, Pakurumọ, Doro webo, Ọsọmọ, Black wood, Ogidiga, Agbara, Bitter Action, Kick and Start. Aleko ati Kerewa.

Kii si se ajeji mọ lati maa ri awọn eeyan, paapa awọn awakọ ero, ọmọ ẹyin ọkọ taa mọ si Kọndọkitọ ati awọn eeyan miran to n sisẹ agbara, ti wọn yoo maa ra ọti lile wọnyi lori atẹ.

Owo awọn ọti lile wọnyi ko ju ara lọ rara, o si bẹrẹ lati aadọta naira si igba naira.

Ni idaji kutukutu si laa ti maa ri awọn awakọ ero, ọlọkada, atawọn eeyan mii, ti wọn yoo maa ra awọn ọti lile yi, ki wọn to bẹrẹ isẹ oojọ wọn.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Ọti lile ko ni anfaani f‘ara

Kinni iwulo awọn ọti lile yi ?

Nigba to n ba ileesẹ BBC sọrọ, Ọgbẹni Anthony Fasọla ni oun maa n ra awọn ọti yi lati fi wo jẹdijẹdi. O ni kii se gbogbo igba ni oun maa nra eroja, nitoripe oun mọ pe o lewu fun agọ ara.

Dokita onisegun oyinbo kan, Adekunle Obilade salaye pe awọn ọti lile ti ọpọ eeyan yan laayo yi lo jẹ ọta ara.

Ẹ gbọ alaye Dokita Obilade siwaju sii.