Igbo Sambisa: Awọn ologun naijiria gbẹ kọngadẹrọ sibẹ

Awọn ologun Naijiria ngbẹ kanga

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán,

Oniruuru ohun eelo amayedẹrun nileesẹ ologun Nigeria n pese sinu igbo Sambisa

Ileesẹ ologun orilẹede Naijiria ti gunle isẹ sisọ igbo Sambisa di igboro.

Ileesẹ ologun orilẹede Naijiria lo kede bẹẹ loju opo ikansira ẹni Twitter rẹ pẹlu afikun pe eyi jẹ ara ọna lati ri daju pe ileesẹ ologun orilẹede yi gba akoso igbo Sambisa patapata kuro lọwọ ikọ adunkoko mọni nni, Boko Haram , to ti fi se ibuba tẹlẹ.

Iroyin naa ni wọn ti la oju ọna sinu igbo ẹru jẹjẹ Sambisa yi, pẹlu ipese omi kanga dẹrọ atawọn ipese ohun eelo amayedẹrun mii eyiti yoo sọ igbẹ Sambisa digboro.

Ileesẹ ologun ni awọn ohun eelo amayedẹrun yi ni yoo wulo fun awọn ọmọsgun orilẹede yi atawọn agbegbe to mule ti igbo Sambisa naa.