Tinubu s'abẹwo si iwọ orun ariwa Naijiria lati yanju aawọ APC

Aworan Wamakko ati Tinubu pẹlu Tambuwal Image copyright Twitter/@Imamimam

Adari agba fun ẹgbẹ ọselu APC lorilẹede Naijiria, Bola Tinubu, ti bẹrẹ igbesẹ lati pari ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa pẹlu sise abẹwo si iwọ orun ariwa Naijiria.

Tinubu se'pade pẹlu gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ati sinetọ Aliyu Wamakko lori bi ija to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni iwọ-orun ariwa Naijiria yoo ti pari.

Iwọ-orun ariwa Naijiria lo ni awọn oludibo to pọ ju lọ l'orilẹede naa.

Ninu awọn ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn lede aiyede laarin wọn ni agbegbe naa ni gomina Kano, Abdullahi Ganduje pẹlu sinetọ Rabiu Kwankwaso, ati gomina Kaduna, Nasir El-Rufai ati sinetọ Shehu Sani.

Tinubu sọ wipe ọrọ bi ẹgbẹ APC yoo se tẹsiwaju ni oun jiroro lori pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Laipẹ yii ni aarẹ Muhammadu Buhari yan Bola Tinubu lati pari ija to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa.