CAN: Darandaran ti ran ida aadọrun ninu ọgọrun ọmọlẹyin Kristi s'ọrun

Ọwọ kan di agbelebu adura mu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán CAN ni ijọ Kristi gbọdọ parapọ nitori awọn ipenija tuntun

Ida aadọrun ninu ọgọrun awọn to ku ninu ọkan-o-jọkan ikolu ipaniyan to waye ni apa ariwa orilẹede Naijiria lo jẹ ọmọlẹyin kristi.

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni orilẹede Naijiria, CAN lo kede to si ni asiko to fun awọn gbogbo igun ati ijọ lati pa ohun pọ sọrọ lori awọn ipaniyan yii.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Agbẹnusọ fun aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni orilẹede Naijiria, CAN, Ẹniọwọ Bayọ Ọladeji ni ti a ba wo awọn ipinlẹ ti ikọlu yii ti sẹlẹ lo fihan wipe awọn agbegbe ti awọn ẹlẹsin kristẹni ti pọ julọ.

" Bi a ba wo awọn ipinlẹ ti isẹlẹ ipaniyan wọn yii ti waye, awọn kristẹni lo pọ julọ nibẹ. Fun apẹẹrẹ, ni ipinlẹ Benue, awọn kristẹni lo pọ ju pẹlu bi ida mejidinlọgọrun ninu ọgọrun awọn eeyan to n gbe ni bẹ, bakanna ni ipinlẹ Taraba bi ida aadọrun ninu ọgọrun awọn eeyan to n gbe ipinlẹ yii ni wọn jẹ Kristẹni nitori asiko ree fun gbogbo wa lati parapọ fi ohun sọkan klori awọn nkan ti o n sẹlẹ ti a ko faramọ."

Ẹgbẹ CAN n sọ ọrọ yii nigba to n fesi lori bi ijọ aguda se pada darapọ mọ ẹgbẹ naa lẹyin to ti fii silẹ fun bi ọdun marun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ CAN gbe iroyin sita wipe ijọ Katoliiki ti pada si aarin rẹ lẹyin ọpọ ifinukonu

Lọjọ aiku ni ẹgbẹ CAN gbe iroyin sita wipe ijọ Katoliiki ti pada si aarin rẹ lẹyin ọpọ ifinukonu.

Ẹgbẹ CAN ni irufẹ isọkan bayii ni ijọ kristọni nilo lati dide lori awọn ohun to wi pe o n sẹlẹ ti 'ko bojumu lorilẹede Naijiria bii aisi ipin oni dọgba-n-dọgba ni bi wọn se pin ipo'

Lori boya idi ti ijọ aguda fi pada darapọ mọọ nii se pẹlu oselu, agbẹnusọ fun ẹgbẹ CAN ni ẹgbẹ naa kii se ẹgbẹ oloselu bi awọn kan se n lero ati wipe idapọ ijọ aguda pẹlu ẹgbẹ naa to ti kọ silẹ lọdun marun sẹyin ko si fun imurasilẹ idibo ọdun 2019.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: