Awọn alatako n beere fun atunto iṣejọba ni Togo

Aarẹ Faure Gnassingbe ti orilẹede Togo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn asoju meje-meje lati ẹgbẹ oselu to n se'jọba pẹlu ẹgbẹ oselu alatako ti gba lati jiroro ni tubiinubi lorilẹede Togo

Lẹyin wahala iwọde to ti n waye lati tako ijọba lorilẹede Togo, ijiroro laarin ẹgbẹ oṣelu to n ṣe'jọba ati ẹgbẹ oṣelu alatako ni ilu Lome tii ṣe olu-ilu orilẹede naa.

Aarẹ orilẹede Ghana Nana Akufo-Addo lo lewaju gẹgẹbi majẹobajẹ nibi iṣide ipade naa.

Ninu ọrọ iṣide rẹ, aarẹ orilẹede Ghana yanana pataki iṣejọba tiwantiwa ati awọn agbekalẹ ijọba ti ko ni kọnu-n-kọhọ ninu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Fun osu marun lawọn ẹgbẹlẹgbẹ oluwọde ti n wọde kaakiri orilẹede togo

Bẹẹ lo tu tọka si bi o ṣe tọ fun awọn eeyan ilẹ Afirika lati maa yanju iṣoro wọn funrawọn.

Aarẹ Nana Akufo-Addo lo ti n ṣe agbodegba ati alarina lasiko wahala ọrọ oṣelu to n waye ni orilẹede Togo.

Awọn aṣoju meje-meje lati ẹgbẹ oṣelu to n ṣe'jọba lorilẹede Togo pẹlu ẹgbẹ oselu alatako nibẹ ni wọn ti gba lati joko jiroro ni tubiinubi bayii lati f'opin si dukuku to n waye lorilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ko din aadọrun eniyan ti wọn mu si atimọle lati igba ti iwọde ti bẹrẹ lorilẹede Togo

Lara awọn koko to wa nilẹ fun eto ijiroro ọhun ni atunto ilana idibo ati ileesẹ ijọba, pẹlu idapada iwe ofin orilẹede naa ti ọdun 1992 eleyi to fun aarẹ yoowu to ba jọ ni anfa saa iṣejọba meji.

Nibayii, awọn asiwaju ẹgbẹ alatako ti leri leka lati kọ ipakọ si ijiroro naa bi ijọba ko ba tu awọn oluwọde ti mu ni gbogbo asiko ti wọn fi se iwọde naa silẹ.

Ko din aadọrun eniyan ti wọn mu si atimọle lati igba ti iwọde naa ti bẹrẹ ni osu kẹjọ ọdun 2017.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ko din ni eeyan mejila ti iku ti pa lasiko iforigbari laarin awọn oluwọde ati awọn agbofinro lorilẹede Togo

Fun osu marun lawọn ẹgbẹlẹgbẹ oluwọde ti n wọde kaakiri orilẹede togo ni agbegbe iwọ oorun ilẹ Afirika lati beere fun fif opin si isejọba alaadọta ọdun ti idile Aarẹ Faure Gnassingbe ti n se nibẹ ati fif gbedeke asiko si saa isejọba aarẹ yoowu ti yoo ba jẹ lorilẹede naa.

Bẹẹni ko din ni eeyan mejila ti iku ti pa lasiko iforigbari laarin awọn oluwọde ati awọn agbofinro nibẹ.