Awọn ero s'ọrọ lori ohun to ṣ'okunfa ijamba baluu Dana

Baluu Dana ni papakọ ofurufu Image copyright @DanaAir
Àkọlé àwòrán Ijamba ọjọ isẹgun ni igbakeji laarin ọsẹ meji ti baluu ileesẹ Dana yoo ma ni ijamba

Lalẹ ọjọ isẹgun ni iroyin kan wipe baluu ileeṣẹ Dana kan ti sare kọja oju opo rẹ ni papakọ ofurufu ilu Port Harcourt.

Meji lara awọn ero inu baluu naa lasiko to sẹlẹ ba BBC Yoruba sọrọ ti wọn si yanana iwa aibikita ati aiṣedede pẹlu asiko irinajo gẹgẹbi ohun gan to f'arahan ninu irinajo naa ati iṣẹlẹ ti o waye.

Ọgbẹni Famous Daunemigha ti o jẹ ero to bọọlẹ gbẹyin ninu baluu naa ṣ'alaye wipe aiṣedede pẹlu akoko ni ohun to fa ijamba yii.

"Ni temi o, kii ṣe wahala oju ọjọ lo ṣ'okunfa iṣẹlẹ yii bikoṣe aiṣedede ileeṣẹ Dana pẹlu akoko irinna wọn. Kani agogo mẹrin ti wọn ti la kalẹ fun irinajo yii ni baluu ti gbera ni, baluu wa yoo ti gunlẹ tipẹtipẹ ki ojo o to de.

Image copyright @DanaAir
Àkọlé àwòrán Awọn ero ni aisedede pẹlu akoko lo koba baluu Dana

"Fun nkan bii oṣu meji bayii ni ileeṣẹ Dana ti n ṣe isunsiwaju awọn akoko irinajo wọn kuro ni akoko ti wọn ti la silẹ. Igba miran wọn a sun irinajo aago mẹrin si meje. Ojoojumọ ni eyi si n ṣẹlẹ.

Ohun kan pato ti mo lee ranti ni wipe, awakọ baluu wa gbiyanju lati ba awọn atọna ọkọ ofurufu ni ile gogoro papakọ ofurufu (Control tower) s'ọrọ ni igba meji ọtọọtọ ṣugbọn wọn ko daa lohun pada.

A balẹ daadaa si ori oju opo irinna baluu ni papakọ ofurufu naa ki o to di wipe a ba ara wa ni inu igbo ti olukuluku si n jijadu fun ẹmi rẹ."

Ọgbẹni Daunemigha ko ṣai bu ẹnu atẹ lu ihuwasi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Dana lẹyin ti iṣẹlẹ ijamba naa ṣẹlẹ. O ni iwa aibikita ti awọn oṣiṣẹ naa hu si awọn ero baluu naa ko fi wọn han gẹgẹbi ileeṣẹ to mọ wipe awọn ero yii ṣẹṣẹ la inu ewu to lagbara kọja ni.

"Nigba ti a jaja bọ silẹ, iyalẹnu lo jẹ wipe ko si oṣiṣẹ ileeṣẹ baluu Dana kankan lati wa bawa sọrọ lori ohun ti o kan. Nṣe ni olukaluku wa nmu ọna wa pọn lọ si ibi ti ẹsẹ dari wa si.

Image copyright PEPPLE NOBLE
Àkọlé àwòrán Awọn ero ni aibikita kan awọn osisẹ Dana

"Mo tun ji de si papakọ ofurufu laarọ yii bayii, ko si ẹnikan ti o tilẹ dide lati bawa sọrọ. Nkan ti mo lee jẹ ni mo n wa bayii. Awọn ẹru mi gan wọn o tii jẹ ki a rii gbe nitori wọn ni awọn ajọ NACAA kan fẹ ṣe ayẹwo. N ṣe ni wọn kan tun n pakun wahala ati iporuru ọkan an wa.

"Ohun to bi ni ninu julọ ni wi pe ko tilẹ si eeyan kan lati ileeṣẹ yii ti o jade lati bawa sọrọ. Ni gbogbo oru, mi o lee sun nitori aworan ohun to ṣẹlẹ yii ko kuro ni ọkan mii.

"Inu iporuru ọkan ni mọ si wa bayii.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ yii ko tilẹ ṣe bi ẹnipe a ṣẹṣẹ la iṣẹlẹ ti ko see fi rẹrin kọja. Inu wahala to da ẹni lọkan ru ni a la kọja ṣugbọn ohun gbogbo ti wọn tun n ṣe yii tun pakun wahala wa."

Ero miran to wa ninu baluu Dana yii lasiko ti o fi sare kọja oju opo rẹ ni ilu PortHarcourt, Praise Etchoga naa ṣalaye wipe iporuru ọkan to ba ọkọọkan awọn ero to wa ninu baluu Dana naa ko kere rara.

Image copyright @DanaAir
Àkọlé àwòrán Awọn ero bu ẹnu atẹ lu ihuwasi awọn osisẹ ileesẹ Dana lẹyin ti isẹlọ ijamba naa sẹlẹ.

Arakunrin Praise Etchoga ti ohun rẹ ṣi n gbọn lasiko to fi n ba BBC Yoruba s'ọrọ ni ibẹru lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ mu ki iya agbalagba kan daku lalẹ ti iṣẹlẹ ijamba naa ṣẹlẹ.

"Nigba ti mo rii wipe nkan ti ri bi o ṣe ri, adura ni mo ko si o. Adura gidigidi pe ki ọlọrun o gba iṣakoso.

Mo padanu ẹrọ ibanisọrọ mi ninu iṣẹlẹ yii.

Gbogbo ẹru wa lo ṣi wa ninu awọn apo irinajo wa ṣugbọn ti wọn ni a ko lee rii gbe bayii nitori ajọ NCAA n ṣe iwadi lọwọ."

Image copyright @DanaAir
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ Dana ni ojo lo fa ijamba baluu wọ̀n ni ilu Portharcourt

Bakanna lo tun ṣalaye wipe pupọ awọn eeyan to wa ninu baluu na ni ko tii le pe awọn eeyan wọn nitori aisi ẹrọ ibanisọrọ wọn.

"Mo padanu ẹrọ ibanisọrọ mi ninu iṣẹlẹ yii. Gbogbo ẹru wa lo ṣi wa ninu awọn apo irinajo wa ṣugbọn ti wọn ni a ko lee rii gbe bayii nitori ajọ NCAA n ṣe iwadi lọwọ.

Bi mo ṣe wayii, mi o mọ iru ipo ti awọn eeyan mi gan maa wa nitori mi o tii ri ẹrọ ibanisọrọ lati pe wọn. Ohun ti mo dẹ bawọn sọ nigba ti mo gbera ni wipe maa pe wọn bi mo ba ti gunlẹ."

Ọkọ baalu ile iṣẹ ofurufu Dana pẹlu nọmba 9J0363, to n lọ lati Abuja si Port harcourt sa're kọja oju opo to si ya wọ inu igbo ni papakọ ofurufu Omagwa; sugbọn awọn alasẹ ni ojo to rọ lo faa.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: