Ikọ̀lu agọ ọlọpa ni South Afrika: Awon yinbọn fun afurasi meje

Awọn ọlọpa South Afrika Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọlu si agọ ọlọpa lọjọru to kọja lo faa ti o fi pọn dandan lati wa awọn afurasi ọdaran ọun

Awọn afurasi meje ti wọn fi ẹsun kan pe wọn seku pa ọlọpa marun ati ologun kan lorilẹede South Afrika ni awọn ọlọpa sọ pe awọn ti yinbọn pa ni ile ijọsin kan.

Lẹyin eyi ni wọn tun ko eeyan mẹwaa s'atimọle lori ọrọ ọun. Awọn oluwadii sọ pe ọwọ tẹ awọn afurasi ọun ni ile ijọsin kan ni abule Nyanga nigba ti awọn toku na papa bora.

Awọn ọlọpa sọ pe ninu ile ijọsin ọun ni awọn ka awọn afurasi ọun mọ.

Oga agba pata fun ile isẹ ọlọpa orilẹede ọun, Khehla John Sitole sọ fun awọn ero nita ile ijọsin ọun pe ile isẹ ọlọpa ti pinnu lati se idajọ to tọ fun awọn afurasi ti wọn seku pa awọn ọlọpa ọun.

Sitole sọ pe ile ise ọlọpa ti sawari awọn oun ija ti awọn afurasi ọun jí kó ni agọ ọlọpa ti wọn se ikọlu si, ati pe, awọn si n wa awọn afurasi to ku ti ọwọ awọn ko tẹ ninu ile ijọsin ọun.

Agbẹnusọ ile isẹ ọlọpa kan ti sọ saaju pe ile ijọsin ọun jẹ ibugbe fun oun to to ọgọrun awọn obirin ati awọn ọmọde, sugbọn ti wọn ko farapa rara ninu isẹlẹ ọun.

Atẹjade ile isẹ ijọba kan sọ pe, awọn agbebọn ọun ti wọn ya wọ agọ ọlọpa ni tosi Mthatha ni wọn sina ibọn fun awọn ọlọpa ti wọn wa lẹnu isẹ, ti wọn si pa mẹta loju ẹsẹ.

Bakan naa ni wọn seku pa ologun kan ti ko si lẹnu isẹ, lẹyin eyi ni wọn ri oku awọn ọlọpa meji ti awọn agbesunmọmi ọun gbe lọ.

Awọn alasẹ sọ pe wọn ko tii mọ idi ikọlu ọun, sugbọn ti wọn lero pe awọn afurasi ọun ti jale nidi ẹro owó kan ko to wa di pe wọn kọlu agọ ọlọpa ọun, nibi ti wọn ti ji awọn oun ija ati ọkọ̀ ọlọpa kan gbe.