Manchester United pada si ipo keji lẹyin to bori Chelsea

Jesse Lingard fi ori kan bọọlu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lingard wọle lati jawe olubori fun Manchester United

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United pada si ipo keji ninu atẹ igbelewọn liigi premiership ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti agbabọọlu rẹ, Jesse Lingard gba ayo to fun un ni isẹgun lori Chelsea wọle ni papa isire Old Trafford.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ni lati se ara giri ni lẹyin ti Willain ti kọkọ gbe Chelsea lewaju ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lukaku jẹwọ akin ninu ifẹsẹwọsẹ pẹlu Chelsea

Manchester united gberasọ ki abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa to pari nigbati ata-matase ikọ naa, Romelu Lukaku gba ayo kan wọle, ki o to di wipe Alvaro Morata gba ayo kan wọle fun Chelsea sugbọn ti oludari ifẹsẹwọnsẹ naa kuna lati gbaa wọle.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si awuyewuye laarin awn olukni ik mejeeji ggbi awn eeyan se n reti saaju ifsẹwọnsẹ naa

Lukaku lo gba bọọlu fun Jesse Lingard lati fi ori kan an wọle nigbati o ku isẹju marundinlogun ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari.

Ohun ti awọn olukọni ikọ mejeeji sọ

Olukọni ikọ Manchester United, Jose Mourinhl sọ wipe:

"Ko si pataki kan nibẹ tori pe o jẹ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, sugbọn o se pataki nitoripe a gbo ewuro si oju ikọ to jẹ olubori ni liigi yii lọwọlọwọ ati pe ami

Lootọ a ko bẹrẹ daadaa sugbọn a bọ si aaye to yẹ bi ifẹsẹwọnsẹ naa ti se n tẹsiwaju."

mẹta ti a nilo lati pada si ipo keji niyi. Awọn agbabọọlu mi fi gbogbo ara si ifẹsẹwọnsẹ naa nitori ko seese lati bori Chelsea laini iru ayo ti a gba loni.

Olukọni ikọ Chelsea, Antonio Conte sọ wipe:

" Anfani nla si silẹ fun wa lati gba esi to dara ninu ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu Manchester Uniter sugbọn dipo eyi ifidirẹmi la mu bọ nibẹ.

Kii se abala kan soso leeyan nilo lati bori ifẹsẹwọnsẹ, o gbọdọ kun oju iwọn lati ibẹẹrẹ titi de opin.nibayii, isoro ni lati gba ife ẹyẹ liigi mọ pẹlu bi ọrọ se ri bayii. Ohun ti o ku lati ja fun naa ni ife ẹyẹ Champions league. Igbagbọ mi ni wipe awọn agbabọọlu pẹlu mọ eyi."

Pẹlu ifidirẹmi yii, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea yoo wa ni ipo karun lori atẹ igbelewọn liigi Premiership lẹyin ti Tottenham bori Crystal Palace pẹlu ami ayo kan saaju ni ọjọ aiku.