'Awọn alagbara lo wa lẹyin ikọlu Dapchi'-Afẹnifẹre

Patako atọnisọna ileewe Dapchi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iromi to njo loju omi, onilu rẹ wa labẹ odo - Afẹnifẹre

Ẹgbẹ Afenifere ti sọ wipe ijinigbe to waye nipinlẹ Yobe jẹ iṣẹ ọwọ awọn alagbara kan lorilẹede Naijiria.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo wipe ohun ti o ba jọ ohun ni a fii we ohun, nitoripe ọrọ naa jọ ti awọn ọmọ ti wọn jigbe ni ilu Chibok nipinlẹ Borno ni ọdun 2014.

Odumakin ṣalaye wipe "o jẹ ohun kayeefi wipe awọn eniyan kan lee ko awọn eniyan ti o le ni ọgọrun ti ọlọpa kankan ko ri wọn. Ati wipe iromi to njo loju omi, onilu rẹ wa labẹ odo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin: Awọn alagbara lo wa lẹyin ijinigbe Dapchi

"Eyi fihan wipe Naijiria ko si ni alaafia. Awọn alagbara nla kan ni won wa nidi oro yi lo fi jẹ ki o ṣeeṣe bi i ti Chibok"

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn aadọfa akẹkọ ni ijọba kede wipe wọn ko tii ri bayi

Lori ọrọ igbiyanju fun ijọba, Odunmakin wipe "ijọba yii ṣoroo gba lamọran".

O bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe ngbowo fun ikọ boko haram lati lee fi awọn ọmọ ti wọn jigbe ni Chibok silẹ. O ṣe iranileti wipe ni ọdun 2014, aarẹ Buhari tako igbogunti awọn ikọ Boko Haram pẹlu aṣẹ ti aarẹ ana Goodluck Jonathan pa.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: