Ikọgosi Ekiti: Itan nipa omi gbigbona ati omi tutu

Ikọgosi Ekiti: Itan nipa omi gbigbona ati omi tutu

Ilu ikọgọsi Ekiti lo gbajugbaja, to si tun jẹ ibudo igbafẹ nitori omi odo kan to nmu omi gbigbona ati tutu jade.

Gẹgẹbi ẹnikan to sọrọ nipa odo naa ti wi, tiyale-tiyawo (Awọ ati Awẹle) ni wọn di omi Ikọgọsi.

O ni awọn eeyan maa nwa lati origun mẹrẹẹrin agbaye ni ojoojumọ lati bu omi Ikọgọsi fun iwosan.

Bakan naa ni ibudo igbafẹ yii npa owo ribiribi wọle fun ijọba ipinlẹ Ekiti.