INEC salaye igbaradi fun ibo gomina nipinlẹ Ekiti

Kaadi idibo lorilẹede Naijiria Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Eto idibo ipinlẹ Ekiti nbọ lọna sugbọn awọn oludibo ko gba kaadi ibo wọn

Bi ipinlẹ Ekiti se n gbaradi fun idibo gomina losu keje ọdun 2018, ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria, INEC ti ke gbajare sita wipe, o le ni ẹgbẹrun lọna igba kaadi oludibo to si wa nilẹ ti awọn eeyan to ni wọn ko tii wa gba bayii ni ipinlẹ naa.

Alamojuto ajọ INEC ni ipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Abulganiyu Ọlayinka-Raji lo sọ eyi di mimọ nilu Ado Ekiti lasiko to fi n ba awọn oniroyin sọrọ lori ibi ti igbaradi de duro fun idibo sipo gomina ni ipinlẹ naa.

Gẹgẹbi ilakalẹ ajọ INEC saaju akoko yii, ọjọ kẹrinla osu keje ọdun 2018 ni eto idibo yoo maa waye lati mọ gomina tuntun fun ipinlẹ Ekiti.

Ọjọgbọ Raji to gbẹnu alukoro ajọ naa, ọgbẹni Taiwo Gbadegẹsin sọrọ ni iha kokanmi ti awọn eeyan n kọ si eto idibo naa, nipa aibikita lati gba kaadi oludibo wọn n kọ ajọ naa lominu gidigidi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ kẹrinla osu keje ọdun 2018 ni eto idibo yoo maa waye lati mọ gomina tuntun fun ipinlẹ Ekiti

Ajọ INEC ni ipinlẹ Ekiti ni awọn ti n pawọpọ pẹlu awọn lọbalọba, ileejọsin gbogbo, ẹgbẹ oselu ati awọn ileesẹ iroyin ni ipinlẹ naa lati lee tubọ rii wi pe ata ati iyọ dun eto ipolongo ati ilanilọyẹ f'awọn oludibo ni ipinlẹ Ekiti.

Alamojuto ajọ INEC ni ipinlẹ Ekiti to tun salaye lori awuyewuye to n waye lori pe awọn majesin n dibo lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria, ko saye fun eyi lasiko idibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ ọhun ni osu keje.

O ni amojuto to peye wa fun eto iforukọsilẹ awọn oludibo to n lọ lọwọ lati dena iforukọsilẹ awọn ti ọjọ ori wọn ko tii pe ọdun mejidinlogun.