Sultan Sokoto: Iyawo ologun ni isẹ lati se fun aseyọri eto abo

Awọn iyawo ologun n kunlẹ ki sultan ilu Sokoto

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán,

Sultan sokoto ke sawọn iyawo ologun lati dide bẹrẹ si ni se itọju awọn to fara kaasa ikọlu igbesumọmi lorilẹede Naijiria

Sultan ti ilu Sokoto, Alhaji Mohammed Saad Abubakar III ti pe fun atilẹyin to giriki f'awọn ologun to n foju wina ija kaakiri ibi ti ina wahala ti n ru lorilẹede yii.

Sultan Saad Abubakar III ni irufẹ atilẹyin bẹẹ ko yọ awọn iyawo ati mọlẹbi awọn ologun naa silẹ.

Sultan pe ipe yii lasiko to fi n gba alejo ẹgbẹ awọn aya ọmọogun lorilẹede Naijiria, NAOWA ti Abilekọ Tukur Buratai lewaju fun ni aafin rẹ ni ilu Sokoto ni iha iwọoorun ariwa orilẹede Naijiria.

Sultan salaye wipe awọn iyawo awọn ọmọogun lorilẹede Naijiria ni ipa pupọ lati ko nipa lasiko ti awọn baale wọn wa loju ija, "laisi ile to toro, awọn ọkọ yin ko lee se ojuse wọn gẹgẹ bi o ti yẹ."

Bakanna lo tun ke sawọn iyawo ologun lorilẹede Naijiria lati bẹrẹ si ni se itọju awọn to fara kaasa ikọlu igbesumọmi lorilẹede Naijiria,paapaajulọ awọn alaini iya tabi baba.

Ninu ọrọ tirẹ, iyawo ọgagun agba ileesẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria, Abilekọ Tukur Buratai ni ẹgbẹ awọn iyawo ọmọogun lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ igbesẹ lati ransẹ itọju ati aanu si awọn opo ti ọkọ wọn subu loju ija atawọn akanda ẹda lawujọ.