Dokita Kenya sisẹ abẹ ọpọlọ fun alaisan ti ko yẹ

Aworan okunrin to n gba itọju ni ile iwosan Kenya. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn dokita ti n se isẹ abẹ sisẹ fun wakati diẹ, ki wọn ri asise naa.

Dokita onimọ nipa ọpọlọ kan ni wọn ti kowe fun lati ‘lo gbele rẹ fun igba diẹ’ naa, nitoriwipe o se isẹ abẹ fun ẹni ti ko yẹ ni ile iwosan ijọba ti ‘Kenyetta National Hospital’.

Iroyin sọwipe isẹlẹ naa waye nigba ti wọn gbe Ọkunrin meji digbadigba wọ ile iwosan lọjọ Aiku, ti ọkan lara wọn nilo isẹ abẹ lati yọ ẹjẹ to lọpọ ni ọpọlọ rẹ, nigba ti ekeji si nilo itọju awọn nọọsi lati jẹki ori rẹ to wu lọsi lẹ , ti kosi nilo isẹ abẹ ọpọlọ.

Amọ, idarudapọ orukọ awọn alaisan lo jẹ kii wọn gbe ẹni ti ko yẹ lọsi ori tabili ti wọn si si ọpọlọ rẹ lati se isẹ abẹ fun.

Awọn dokita ti n se isẹ abẹ lo fun wakati diẹ, ko to di wipe wọn sakiyesi wipe ko si ẹjẹ to di pọ si ọpọlọ Ọkunrin ti wọn n se isẹ abẹ fun.

Adari ile-iwosan naa, Lily Koros ninu atejade kan, sọwipe wọn ti kọwe ‘lo gbe ile rẹ naa’ fun awọn osisẹ mẹrin to wa lẹnu isẹ lọjọ ti isẹlẹ naa sẹlẹ.

Ohun iwuri ti iwe iroyin ‘the Nation’ lorilẹede Kenya, sọ ni wipe awọn alaisan mejeeji wa ni alaafia ti wọn sin gba itọju to peye lọwọ.

Related Topics