PDP dẹbi ru ijọba apapọ lori awọn osisẹ aseranwọ to ku ni Rann

wọn gbe oku awọn osisẹ aseranwọ wọnu baluu Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn osisẹ aseranwọ mẹta lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye ni Rann

Egbẹ oselu PDP ti bẹnu atẹ lu bi awọn agbesunmọmi se seku pa ọpọ eniyan, ti o fi mọ awọn osisẹ aseranwọ lati ilẹ okeere ni ilu Rann ni ipinlẹ Borno lọjọbọ to kọja.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, ni agbẹnusọ ẹgbẹ ọun, Kọla Ologbodiyan ti sọ ọrọ ọun ni ọjọ́ abamẹta.

Wọn ni ijọba apapọ̀ ti aarẹ Muhammadu Buhari n dari rẹ̀ ni o yẹ̀ ki ajọ isọkan agbaye di ẹbi iku awọn eniyan ọun le lori.

Egbẹ PDP tun sọ pe, o yẹ ki awọn lajọlajọ ti kii se ti ijọba se iwadii ọrọ ọun, ki wọn se ofintoto ẹsun ti wọn fi kan awọn osisẹ alaabo pe wọn ko sisẹ wọn bi isẹ lawọn agbegbe ọun, ati ẹsun pe awọn asoju ijọba apapọ kan da lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ọun silẹ, eleyi ti o ti mu ọpọlọpọ gbagbọ pe oun lo fa bi ikọlu awọn agbesunmọmi ọun tun se ru soke sii lẹnu ọjọ mẹta yii.

PDP tun bu ẹnu atẹ lu oun ti wọn sapejuwe gẹgẹ bi ọrọ aisọotọ lati ọdọ ijọba apapọ. Wọn ni lẹyin ti ijọba apapọ ti fi lede pe awọn ti koju ikọlu awọn agbesunmọmi nibiti ikọlu ọun ti n waye ni awọn olugbe ni awọn igberiko ati awọn osisẹ miiran lati ilẹ okeere fi ni igbagbọ ninu wọn, lai mọ pe, ẹmi awọn wa ninu ewu.

Egbẹ oselu ọun ni awọn se ibanikẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ọun, ti wọn si kesi awọn ọmọ Naijiria ati awọn lajọlajọ lagbaaye lati se iranlọwọ to tọ fun orilẹede Naijiria.