Awọn arinrinajo Hajj orilẹede Naijiria yoo bẹrẹ si sanwo ori ni Saudi

Awọn arinrinajo Hajj
Àkọlé àwòrán Ijọba ilẹ Saudi mu ni dandan fun awọn aririnajo Hajj lati san ẹgbẹrun meji owo Riyal

Awọn alasẹ ilu Saudi Arabia ti sọ pe, o di dandan fun awọn arinrinajo ti wọn ba wa lati orilẹede Naijiria, ni pataki, awọn ti wọn ti lọ fun Hajj tabi Umrah ni bi ọdun meji sẹyin lati maa san owo to to ẹgbẹrun mẹtalelọgọjọ ni owo Naira.

Abdullahi Mukhtar to jẹ alaga ajọ to n moju to irinajo Hajj sọ pe, o di dandan fun gbogbo ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrinajo ọun lati san owo naa, eyi si yato gbedengbe si owo ti arinrinajo kọọkan yoo san gẹgẹ bi owo irinajo eyi ti ijọba apapọ ko tii kede fun ọdun 2018.

Tun yatọ si owo eyi, awọn alasẹ ilẹ Saudi tun sọ pe, aleekun ida marun yoo gori gbogbo nnkan ti awọn arinrinajo ba fẹ se lasiko Hajj ọun, sugbọn ti eyi ko mọ ounjẹ ati oogun rira.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Irinajo Hajj jẹ ọkan lara opo marun to wa ninu ẹsin Islam

Ni ipinlẹ Sokoto ni Mukhtar, ẹni ti Abdullahi Sale, alamojuto isẹ sisẹ ninu ajọ to n mojuto ọrọ awọn arinrinajo Hajj soju fun ti sọrọ ọun.

O sọ isepataki sisan owo ọun ninu eto kan ti ajọ to n samujo awọn aririnajo lọ silẹ mimọ gbe kalẹ fun awọn ti wọn n gbero lati rinrinajo lọdun yii.

Muktar tun fi kun ọrọ rẹ pe, ofin ọun ti fẹsẹ mulẹ lati igba Hajj ọdun to kọja, ati pe, awọn gbe eto ọun kalẹ lati fi to awọn ti wọn o rinrinajo lọdun 2018 leti.